Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #150 Translated in Yoruba

وَعَلَى الَّذِينَ هَادُوا حَرَّمْنَا كُلَّ ذِي ظُفُرٍ ۖ وَمِنَ الْبَقَرِ وَالْغَنَمِ حَرَّمْنَا عَلَيْهِمْ شُحُومَهُمَا إِلَّا مَا حَمَلَتْ ظُهُورُهُمَا أَوِ الْحَوَايَا أَوْ مَا اخْتَلَطَ بِعَظْمٍ ۚ ذَٰلِكَ جَزَيْنَاهُمْ بِبَغْيِهِمْ ۖ وَإِنَّا لَصَادِقُونَ
A se e ni eewo fun awon t’o di yehudi gbogbo eran eleeekanna (tabi onipatako t’o supo mora won). Ninu eran maalu ati agutan, A tun se ora awon mejeeji ni eewo fun won afi eyi ti o ba le mo eyin won tabi ifun tabi eyi ti o ba ropo mo eegun. Iyen ni A fi san won ni esan nitori abosi owo won. Dajudaju Awa si ni Olododo
فَإِنْ كَذَّبُوكَ فَقُلْ رَبُّكُمْ ذُو رَحْمَةٍ وَاسِعَةٍ وَلَا يُرَدُّ بَأْسُهُ عَنِ الْقَوْمِ الْمُجْرِمِينَ
Ti won ba si pe o ni opuro, so nigba naa pe: "Oluwa yin ni Onikee to gbooro. Ko si si eni t’o le gbe iya Re kuro lori ijo elese
سَيَقُولُ الَّذِينَ أَشْرَكُوا لَوْ شَاءَ اللَّهُ مَا أَشْرَكْنَا وَلَا آبَاؤُنَا وَلَا حَرَّمْنَا مِنْ شَيْءٍ ۚ كَذَٰلِكَ كَذَّبَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ حَتَّىٰ ذَاقُوا بَأْسَنَا ۗ قُلْ هَلْ عِنْدَكُمْ مِنْ عِلْمٍ فَتُخْرِجُوهُ لَنَا ۖ إِنْ تَتَّبِعُونَ إِلَّا الظَّنَّ وَإِنْ أَنْتُمْ إِلَّا تَخْرُصُونَ
Awon t’o n sebo yoo wi pe: "Ti ko ba je pe Allahu ba fe ni awa ati awon baba wa iba ti sebo, ati pe awa iba ti se nnkan kan leewo." Bayen ni awon t’o siwaju won se pe oro Allahu niro titi won fi to iya Wa wo. So pe: "Nje imo kan n be ni odo yin, ki e mu un jade fun wa?" Eyin ko tele kini kan bi ko se aroso. Ki si ni e n so bi ko se pe e n paro
قُلْ فَلِلَّهِ الْحُجَّةُ الْبَالِغَةُ ۖ فَلَوْ شَاءَ لَهَدَاكُمْ أَجْمَعِينَ
So pe: "Ti Allahu ni eri t’o pe perepere." Nitori naa, ti O ba fe ni, iba fi gbogbo yin mona patapata
قُلْ هَلُمَّ شُهَدَاءَكُمُ الَّذِينَ يَشْهَدُونَ أَنَّ اللَّهَ حَرَّمَ هَٰذَا ۖ فَإِنْ شَهِدُوا فَلَا تَشْهَدْ مَعَهُمْ ۚ وَلَا تَتَّبِعْ أَهْوَاءَ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَالَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ وَهُمْ بِرَبِّهِمْ يَعْدِلُونَ
So pe: "E mu awon elerii yin jade, awon t’o maa jerii pe dajudaju Allahu l’o se eyi leewo." Ti won ba jerii (siro), iwo ma se ba won jerii (si i). Ma si se tele ife-inu awon t’o pe awon ayah Wa niro ati awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo. Awon si ni won n ba Oluwa won wa akegbe

Choose other languages: