Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #67 Translated in Yoruba

وَإِذْ أَخَذْنَا مِيثَاقَكُمْ وَرَفَعْنَا فَوْقَكُمُ الطُّورَ خُذُوا مَا آتَيْنَاكُمْ بِقُوَّةٍ وَاذْكُرُوا مَا فِيهِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ
E ranti nigba ti A gba adehun yin, A si gbe apata wa soke ori yin, (A si so pe): “E gba ohun ti A fun yin mu daradara, ki e si ranti ohun t’o wa ninu re, nitori ki e le beru (Allahu)
ثُمَّ تَوَلَّيْتُمْ مِنْ بَعْدِ ذَٰلِكَ ۖ فَلَوْلَا فَضْلُ اللَّهِ عَلَيْكُمْ وَرَحْمَتُهُ لَكُنْتُمْ مِنَ الْخَاسِرِينَ
Leyin naa, e peyinda leyin iyen. Ti ki i ba se oore ajulo Allahu ati aanu Re lori yin, eyin iba wa ninu eni ofo
وَلَقَدْ عَلِمْتُمُ الَّذِينَ اعْتَدَوْا مِنْكُمْ فِي السَّبْتِ فَقُلْنَا لَهُمْ كُونُوا قِرَدَةً خَاسِئِينَ
Dajudaju e mo awon t’o koja enu-ala ninu yin nipa ojo Sabt. A si so fun won pe: "E di obo, eni-igbejinna si ike
فَجَعَلْنَاهَا نَكَالًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهَا وَمَا خَلْفَهَا وَمَوْعِظَةً لِلْمُتَّقِينَ
A si se e ni arikogbon fun eni t’o soju re ati eni t’o n bo leyin re. (O tun je) eko fun awon oluberu (Allahu)
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُكُمْ أَنْ تَذْبَحُوا بَقَرَةً ۖ قَالُوا أَتَتَّخِذُنَا هُزُوًا ۖ قَالَ أَعُوذُ بِاللَّهِ أَنْ أَكُونَ مِنَ الْجَاهِلِينَ
(E ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: “Dajudaju Allahu n pa yin ni ase pe ki e pa abo maalu kan.” Won wi pe: “Se o n fi wa se yeye ni!” O so pe: "Mo n sadi Allahu nibi ki ng je ara awon ope

Choose other languages: