Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #70 Translated in Yoruba

فَجَعَلْنَاهَا نَكَالًا لِمَا بَيْنَ يَدَيْهَا وَمَا خَلْفَهَا وَمَوْعِظَةً لِلْمُتَّقِينَ
A si se e ni arikogbon fun eni t’o soju re ati eni t’o n bo leyin re. (O tun je) eko fun awon oluberu (Allahu)
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ إِنَّ اللَّهَ يَأْمُرُكُمْ أَنْ تَذْبَحُوا بَقَرَةً ۖ قَالُوا أَتَتَّخِذُنَا هُزُوًا ۖ قَالَ أَعُوذُ بِاللَّهِ أَنْ أَكُونَ مِنَ الْجَاهِلِينَ
(E ranti) nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: “Dajudaju Allahu n pa yin ni ase pe ki e pa abo maalu kan.” Won wi pe: “Se o n fi wa se yeye ni!” O so pe: "Mo n sadi Allahu nibi ki ng je ara awon ope
قَالُوا ادْعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّنْ لَنَا مَا هِيَ ۚ قَالَ إِنَّهُ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٌ لَا فَارِضٌ وَلَا بِكْرٌ عَوَانٌ بَيْنَ ذَٰلِكَ ۖ فَافْعَلُوا مَا تُؤْمَرُونَ
Won wi pe: “Pe Oluwa re fun wa, ki O fi ye wa, ewo ni.” O so pe: "Dajudaju O n so pe abo maalu ni. Ko nii je ogbologboo, ko si nii je godogbo. O maa wa laaarin (mejeeji) yen. Nitori naa, e se ohun ti Won n pa yin lase
قَالُوا ادْعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّنْ لَنَا مَا لَوْنُهَا ۚ قَالَ إِنَّهُ يَقُولُ إِنَّهَا بَقَرَةٌ صَفْرَاءُ فَاقِعٌ لَوْنُهَا تَسُرُّ النَّاظِرِينَ
Won wi pe: “Pe Oluwa re fun wa, ki O fi ye wa, ki ni awo re.” O so pe: “Dajudaju O n so pe abo maalu, alawo omi-osan ni. Awo re yo si mo fonifoni, ti o maa dun-un wo l’oju awon oluworan
قَالُوا ادْعُ لَنَا رَبَّكَ يُبَيِّنْ لَنَا مَا هِيَ إِنَّ الْبَقَرَ تَشَابَهَ عَلَيْنَا وَإِنَّا إِنْ شَاءَ اللَّهُ لَمُهْتَدُونَ
Won wi pe: "Pe Oluwa re fun wa, ki O fi ye wa, ewo ni. Dajudaju awon abo maalu jora won loju wa. Ati pe dajudaju, ti Allahu ba fe, awa maa mona (ti a o gba ri i)

Choose other languages: