Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #40 Translated in Yoruba

فَأَزَلَّهُمَا الشَّيْطَانُ عَنْهَا فَأَخْرَجَهُمَا مِمَّا كَانَا فِيهِ ۖ وَقُلْنَا اهْبِطُوا بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ ۖ وَلَكُمْ فِي الْأَرْضِ مُسْتَقَرٌّ وَمَتَاعٌ إِلَىٰ حِينٍ
Amo Esu ye awon mejeeji lese kuro ninu Ogba Idera, o si mu won jade kuro ninu ibi ti won wa. A si so pe: "E sokale, ota ni apa kan yin je fun apa kan. Ibugbe ati nnkan igbadun si n be fun yin lori ile fun igba (die).”
فَتَلَقَّىٰ آدَمُ مِنْ رَبِّهِ كَلِمَاتٍ فَتَابَ عَلَيْهِ ۚ إِنَّهُ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ
Leyin naa, (Anabi) Adam ri awon oro kan gba lati odo Oluwa re. O si gba ironupiwada re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun
قُلْنَا اهْبِطُوا مِنْهَا جَمِيعًا ۖ فَإِمَّا يَأْتِيَنَّكُمْ مِنِّي هُدًى فَمَنْ تَبِعَ هُدَايَ فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
A so pe : “Gbogbo yin, e sokale kuro ninu re. Nigba ti imona ba de ba yin lati odo Mi, eni ti o ba tele imona Mi, ipaya ko nii si fun won. Won ko si nii banuje
وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Awon t’o ba si sai gbagbo, ti won si pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re.”
يَا بَنِي إِسْرَائِيلَ اذْكُرُوا نِعْمَتِيَ الَّتِي أَنْعَمْتُ عَلَيْكُمْ وَأَوْفُوا بِعَهْدِي أُوفِ بِعَهْدِكُمْ وَإِيَّايَ فَارْهَبُونِ
Eyin omo ’Isro’il, e ranti idera Mi, eyi ti Mo se fun yin. E mu majemu Mi se, Mo maa mu (esan) majemu yin se. Emi nikan ni ki e si paya

Choose other languages: