Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #39 Translated in Yoruba

وَقُلْنَا يَا آدَمُ اسْكُنْ أَنْتَ وَزَوْجُكَ الْجَنَّةَ وَكُلَا مِنْهَا رَغَدًا حَيْثُ شِئْتُمَا وَلَا تَقْرَبَا هَٰذِهِ الشَّجَرَةَ فَتَكُونَا مِنَ الظَّالِمِينَ
A si so pe: “Adam, iwo ati iyawo re, e maa gbe ninu Ogba Idera. Ki e maa je ninu re ni gbedemuke ni ibikibi ti e ba fe. Ki e si ma se sunmo igi yii, ki e ma baa wa ninu awon alabosi.”
فَأَزَلَّهُمَا الشَّيْطَانُ عَنْهَا فَأَخْرَجَهُمَا مِمَّا كَانَا فِيهِ ۖ وَقُلْنَا اهْبِطُوا بَعْضُكُمْ لِبَعْضٍ عَدُوٌّ ۖ وَلَكُمْ فِي الْأَرْضِ مُسْتَقَرٌّ وَمَتَاعٌ إِلَىٰ حِينٍ
Amo Esu ye awon mejeeji lese kuro ninu Ogba Idera, o si mu won jade kuro ninu ibi ti won wa. A si so pe: "E sokale, ota ni apa kan yin je fun apa kan. Ibugbe ati nnkan igbadun si n be fun yin lori ile fun igba (die).”
فَتَلَقَّىٰ آدَمُ مِنْ رَبِّهِ كَلِمَاتٍ فَتَابَ عَلَيْهِ ۚ إِنَّهُ هُوَ التَّوَّابُ الرَّحِيمُ
Leyin naa, (Anabi) Adam ri awon oro kan gba lati odo Oluwa re. O si gba ironupiwada re. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun
قُلْنَا اهْبِطُوا مِنْهَا جَمِيعًا ۖ فَإِمَّا يَأْتِيَنَّكُمْ مِنِّي هُدًى فَمَنْ تَبِعَ هُدَايَ فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
A so pe : “Gbogbo yin, e sokale kuro ninu re. Nigba ti imona ba de ba yin lati odo Mi, eni ti o ba tele imona Mi, ipaya ko nii si fun won. Won ko si nii banuje
وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Awon t’o ba si sai gbagbo, ti won si pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re.”

Choose other languages: