Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #211 Translated in Yoruba

وَمِنَ النَّاسِ مَنْ يَشْرِي نَفْسَهُ ابْتِغَاءَ مَرْضَاتِ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ رَءُوفٌ بِالْعِبَادِ
O n be ninu awon eniyan, eni t’o n ta emi ara re lati wa iyonu Allahu. Allahu si ni Alaaanu fun awon erusin (Re)
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا ادْخُلُوا فِي السِّلْمِ كَافَّةً وَلَا تَتَّبِعُوا خُطُوَاتِ الشَّيْطَانِ ۚ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُبِينٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ko s’inu esin ’Islam patapata. Eyin ko si gbodo tele oju-ese Esu. Dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin
فَإِنْ زَلَلْتُمْ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَتْكُمُ الْبَيِّنَاتُ فَاعْلَمُوا أَنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Nitori naa, ti ese yin ba ye (kuro ninu ’Islam) leyin ti awon eri t’o yanju ti de ba yin, ki e mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon
هَلْ يَنْظُرُونَ إِلَّا أَنْ يَأْتِيَهُمُ اللَّهُ فِي ظُلَلٍ مِنَ الْغَمَامِ وَالْمَلَائِكَةُ وَقُضِيَ الْأَمْرُ ۚ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ
Se won n reti kini kan bi ko se pe ki Allahu wa ba won ninu iboji esujo, awon molaika naa (si maa wa, nigba naa) A o si yanju oro (isiro ise eda)! Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si
سَلْ بَنِي إِسْرَائِيلَ كَمْ آتَيْنَاهُمْ مِنْ آيَةٍ بَيِّنَةٍ ۗ وَمَنْ يُبَدِّلْ نِعْمَةَ اللَّهِ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَتْهُ فَإِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ
Bi awon omo ’Isro’il leere pe: “Meloo ni A ti fun won ninu ayah t’o yanju?” Enikeni ti o ba (fi aigbagbo) jiro idera Allahu leyin ti o de ba a, dajudaju Allahu le (nibi) iya

Choose other languages: