Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #214 Translated in Yoruba

هَلْ يَنْظُرُونَ إِلَّا أَنْ يَأْتِيَهُمُ اللَّهُ فِي ظُلَلٍ مِنَ الْغَمَامِ وَالْمَلَائِكَةُ وَقُضِيَ الْأَمْرُ ۚ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ
Se won n reti kini kan bi ko se pe ki Allahu wa ba won ninu iboji esujo, awon molaika naa (si maa wa, nigba naa) A o si yanju oro (isiro ise eda)! Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si
سَلْ بَنِي إِسْرَائِيلَ كَمْ آتَيْنَاهُمْ مِنْ آيَةٍ بَيِّنَةٍ ۗ وَمَنْ يُبَدِّلْ نِعْمَةَ اللَّهِ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَتْهُ فَإِنَّ اللَّهَ شَدِيدُ الْعِقَابِ
Bi awon omo ’Isro’il leere pe: “Meloo ni A ti fun won ninu ayah t’o yanju?” Enikeni ti o ba (fi aigbagbo) jiro idera Allahu leyin ti o de ba a, dajudaju Allahu le (nibi) iya
زُيِّنَ لِلَّذِينَ كَفَرُوا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا وَيَسْخَرُونَ مِنَ الَّذِينَ آمَنُوا ۘ وَالَّذِينَ اتَّقَوْا فَوْقَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ وَاللَّهُ يَرْزُقُ مَنْ يَشَاءُ بِغَيْرِ حِسَابٍ
Won se isemi aye ni oso (etan) fun awon alaigbagbo. (Ti aye ba si ye won tan,) won yo maa fi awon t’o gbagbo ni ododo se yeye. Awon t’o si beru Allahu maa wa l’oke won ni Ojo Ajinde. Ati pe Allahu n pese arisiki fun eni ti O ba fe lai la isiro lo
كَانَ النَّاسُ أُمَّةً وَاحِدَةً فَبَعَثَ اللَّهُ النَّبِيِّينَ مُبَشِّرِينَ وَمُنْذِرِينَ وَأَنْزَلَ مَعَهُمُ الْكِتَابَ بِالْحَقِّ لِيَحْكُمَ بَيْنَ النَّاسِ فِيمَا اخْتَلَفُوا فِيهِ ۚ وَمَا اخْتَلَفَ فِيهِ إِلَّا الَّذِينَ أُوتُوهُ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَتْهُمُ الْبَيِّنَاتُ بَغْيًا بَيْنَهُمْ ۖ فَهَدَى اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا لِمَا اخْتَلَفُوا فِيهِ مِنَ الْحَقِّ بِإِذْنِهِ ۗ وَاللَّهُ يَهْدِي مَنْ يَشَاءُ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ
Awon eniyan je ijo kan soso (elesin ’Islam nipile). Allahu si gbe awon Anabi dide ni oniroo idunnu ati olukilo. O so Tira kale fun won pelu ododo nitori ki O le fi se idajo laaarin awon eniyan nipa ohun ti won yapa enu si. Ko si si eni t’o yapa enu (si ’Islam) afi awon ti A fun ni Tira, leyin ti awon eri t’o yanju de ba won. (Won se bee) nipase ote aarin won (si awon Anabi). Nitori naa, Allahu to awon t’o gbagbo ni ododo sona pelu iyonda Re nipa ohun ti awon olote1 yapa enu si nipa ododo (’Islam). Allahu yo maa to eni ti O ba fe si ona taara
أَمْ حَسِبْتُمْ أَنْ تَدْخُلُوا الْجَنَّةَ وَلَمَّا يَأْتِكُمْ مَثَلُ الَّذِينَ خَلَوْا مِنْ قَبْلِكُمْ ۖ مَسَّتْهُمُ الْبَأْسَاءُ وَالضَّرَّاءُ وَزُلْزِلُوا حَتَّىٰ يَقُولَ الرَّسُولُ وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ مَتَىٰ نَصْرُ اللَّهِ ۗ أَلَا إِنَّ نَصْرَ اللَّهِ قَرِيبٌ
Tabi e lero pe e maa wo inu Ogba Idera nigba ti irufe (adanwo) t’o kan awon t’o ti lo siwaju yin ko ti i kan yin? Iponju ati ailera mu won. Won si ri amiwo to bee ge ti Ojise ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re fi so pe: “Igba wo ni aranse Allahu maa de se?” Kiye si i! Dajudaju aranse Allahu sunmo

Choose other languages: