Surah An-Nisa Ayahs #145 Translated in Yoruba
الَّذِينَ يَتَرَبَّصُونَ بِكُمْ فَإِنْ كَانَ لَكُمْ فَتْحٌ مِنَ اللَّهِ قَالُوا أَلَمْ نَكُنْ مَعَكُمْ وَإِنْ كَانَ لِلْكَافِرِينَ نَصِيبٌ قَالُوا أَلَمْ نَسْتَحْوِذْ عَلَيْكُمْ وَنَمْنَعْكُمْ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ ۚ فَاللَّهُ يَحْكُمُ بَيْنَكُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ ۗ وَلَنْ يَجْعَلَ اللَّهُ لِلْكَافِرِينَ عَلَى الْمُؤْمِنِينَ سَبِيلًا
(Awon ni) awon t’o fe yo yin; ti isegun kan lati odo Allahu ba je tiyin, won a wi pe: “Se awa ko wa pelu yin bi?” Ti ipin kan ba si wa fun awon alaigbagbo, (awon munaafiki) a wi pe: “Se awa ko ti ni ikapa lati je gaba le yin lori (amo ti awa ko se bee), se awa ko si daabo bo yin to lowo awon onigbagbo ododo (titi owo yin fi ba oro-ogun, nitori naa ki ni ipin tiwa ti e fe fun wa?)” Nitori naa, Allahu yoo sedajo laaarin yin ni Ojo Ajinde. Allahu ko si nii fun awon alaigbagbo ni ona (isegun) kan lori awon onigbagbo ododo
إِنَّ الْمُنَافِقِينَ يُخَادِعُونَ اللَّهَ وَهُوَ خَادِعُهُمْ وَإِذَا قَامُوا إِلَى الصَّلَاةِ قَامُوا كُسَالَىٰ يُرَاءُونَ النَّاسَ وَلَا يَذْكُرُونَ اللَّهَ إِلَّا قَلِيلًا
Dajudaju awon sobe-selu musulumi n tan Allahu, Oun naa si maa tan won. Nigba ti won ba duro lati kirun, won a duro (ni iduro) oroju, won yo si maa se sekarimi (lori irun). Won ko si nii se (gbolohun) iranti Allahu (lori irun) afi die
مُذَبْذَبِينَ بَيْنَ ذَٰلِكَ لَا إِلَىٰ هَٰؤُلَاءِ وَلَا إِلَىٰ هَٰؤُلَاءِ ۚ وَمَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَلَنْ تَجِدَ لَهُ سَبِيلًا
Won n se balabala sihin-in sohun-un, won ko je ti awon wonyi, won ko si je ti awon wonyi. Enikeni ti Allahu ba si lona, o o si nii ri ona kan fun un
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا الْكَافِرِينَ أَوْلِيَاءَ مِنْ دُونِ الْمُؤْمِنِينَ ۚ أَتُرِيدُونَ أَنْ تَجْعَلُوا لِلَّهِ عَلَيْكُمْ سُلْطَانًا مُبِينًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon alaigbagbo ni ore ayo leyin awon onigbagbo ododo (egbe yin). Se e fe se nnkan ti Allahu yoo fi ni eri ponnbele lowo lati je yin niya ni
إِنَّ الْمُنَافِقِينَ فِي الدَّرْكِ الْأَسْفَلِ مِنَ النَّارِ وَلَنْ تَجِدَ لَهُمْ نَصِيرًا
Dajudaju awon sobe-selu musulumi yoo wa ninu aja isale patapata ninu Ina. O o si nii ri alaranse kan fun won
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
