Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #146 Translated in Yoruba

إِنَّ الْمُنَافِقِينَ يُخَادِعُونَ اللَّهَ وَهُوَ خَادِعُهُمْ وَإِذَا قَامُوا إِلَى الصَّلَاةِ قَامُوا كُسَالَىٰ يُرَاءُونَ النَّاسَ وَلَا يَذْكُرُونَ اللَّهَ إِلَّا قَلِيلًا
Dajudaju awon sobe-selu musulumi n tan Allahu, Oun naa si maa tan won. Nigba ti won ba duro lati kirun, won a duro (ni iduro) oroju, won yo si maa se sekarimi (lori irun). Won ko si nii se (gbolohun) iranti Allahu (lori irun) afi die
مُذَبْذَبِينَ بَيْنَ ذَٰلِكَ لَا إِلَىٰ هَٰؤُلَاءِ وَلَا إِلَىٰ هَٰؤُلَاءِ ۚ وَمَنْ يُضْلِلِ اللَّهُ فَلَنْ تَجِدَ لَهُ سَبِيلًا
Won n se balabala sihin-in sohun-un, won ko je ti awon wonyi, won ko si je ti awon wonyi. Enikeni ti Allahu ba si lona, o o si nii ri ona kan fun un
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَتَّخِذُوا الْكَافِرِينَ أَوْلِيَاءَ مِنْ دُونِ الْمُؤْمِنِينَ ۚ أَتُرِيدُونَ أَنْ تَجْعَلُوا لِلَّهِ عَلَيْكُمْ سُلْطَانًا مُبِينًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se mu awon alaigbagbo ni ore ayo leyin awon onigbagbo ododo (egbe yin). Se e fe se nnkan ti Allahu yoo fi ni eri ponnbele lowo lati je yin niya ni
إِنَّ الْمُنَافِقِينَ فِي الدَّرْكِ الْأَسْفَلِ مِنَ النَّارِ وَلَنْ تَجِدَ لَهُمْ نَصِيرًا
Dajudaju awon sobe-selu musulumi yoo wa ninu aja isale patapata ninu Ina. O o si nii ri alaranse kan fun won
إِلَّا الَّذِينَ تَابُوا وَأَصْلَحُوا وَاعْتَصَمُوا بِاللَّهِ وَأَخْلَصُوا دِينَهُمْ لِلَّهِ فَأُولَٰئِكَ مَعَ الْمُؤْمِنِينَ ۖ وَسَوْفَ يُؤْتِ اللَّهُ الْمُؤْمِنِينَ أَجْرًا عَظِيمًا
Ayafi awon t’o ronu piwada, ti won se atunse, ti won duro sinsin ti Allahu, ti won si se afomo esin won fun Allahu. Nitori naa, awon wonyen maa wa pelu awon onigbagbo ododo. Laipe Allahu maa fun awon onigbagbo ododo ni esan nla

Choose other languages: