Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Qasas Ayahs #25 Translated in Yoruba

فَخَرَجَ مِنْهَا خَائِفًا يَتَرَقَّبُ ۖ قَالَ رَبِّ نَجِّنِي مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
O si jade kuro ninu (ilu) pelu ipaya, ti o n reti (ehonu won), o si so pe: “Oluwa mi, la mi lowo ijo alabosi.”
وَلَمَّا تَوَجَّهَ تِلْقَاءَ مَدْيَنَ قَالَ عَسَىٰ رَبِّي أَنْ يَهْدِيَنِي سَوَاءَ السَّبِيلِ
Nigba ti o si doju ko okankan ilu Modyan, o so pe: “O sunmo ki Oluwa mi fona taara (si ilu Modyan) mo mi.”
وَلَمَّا وَرَدَ مَاءَ مَدْيَنَ وَجَدَ عَلَيْهِ أُمَّةً مِنَ النَّاسِ يَسْقُونَ وَوَجَدَ مِنْ دُونِهِمُ امْرَأَتَيْنِ تَذُودَانِ ۖ قَالَ مَا خَطْبُكُمَا ۖ قَالَتَا لَا نَسْقِي حَتَّىٰ يُصْدِرَ الرِّعَاءُ ۖ وَأَبُونَا شَيْخٌ كَبِيرٌ
Nigba ti o de ibi (kannga) omi (ilu) Modyan, o ba ijo eniyan kan nibe ti won n fun awon eran-osin won ni omi mu. Leyin won, o tun ri awon obinrin meji kan ti won n fa seyin (pelu eran-osin won). O so pe: “Ki l’o se eyin mejeeji?” Won so pe: “A o le fun awon eran-osin wa ni omi mu titi awon adaran ba to ko awon eran-osin won lo. Agbalagba arugbo si ni baba wa.”
فَسَقَىٰ لَهُمَا ثُمَّ تَوَلَّىٰ إِلَى الظِّلِّ فَقَالَ رَبِّ إِنِّي لِمَا أَنْزَلْتَ إِلَيَّ مِنْ خَيْرٍ فَقِيرٌ
O si ba won fun (eran-osin) won ni omi mu. Leyin naa, o pada sibi iboji, o si so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi bukata si ohun ti O ba sokale fun mi ninu oore.”
فَجَاءَتْهُ إِحْدَاهُمَا تَمْشِي عَلَى اسْتِحْيَاءٍ قَالَتْ إِنَّ أَبِي يَدْعُوكَ لِيَجْزِيَكَ أَجْرَ مَا سَقَيْتَ لَنَا ۚ فَلَمَّا جَاءَهُ وَقَصَّ عَلَيْهِ الْقَصَصَ قَالَ لَا تَخَفْ ۖ نَجَوْتَ مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
Okan ninu awon mejeeji wa ba a, o si n rin pelu itiju, o so pe: “Dajudaju baba mi n pe o nitori ki o le san o ni esan omi ti o fun (awon eran-osin) wa mu.” Nigba ti o de odo re, o so itan (ara re) fun un. (Baba naa) so pe: “Ma beru. O ti la lowo ijo alabosi.”

Choose other languages: