Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Qasas Ayahs #28 Translated in Yoruba

فَسَقَىٰ لَهُمَا ثُمَّ تَوَلَّىٰ إِلَى الظِّلِّ فَقَالَ رَبِّ إِنِّي لِمَا أَنْزَلْتَ إِلَيَّ مِنْ خَيْرٍ فَقِيرٌ
O si ba won fun (eran-osin) won ni omi mu. Leyin naa, o pada sibi iboji, o si so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi bukata si ohun ti O ba sokale fun mi ninu oore.”
فَجَاءَتْهُ إِحْدَاهُمَا تَمْشِي عَلَى اسْتِحْيَاءٍ قَالَتْ إِنَّ أَبِي يَدْعُوكَ لِيَجْزِيَكَ أَجْرَ مَا سَقَيْتَ لَنَا ۚ فَلَمَّا جَاءَهُ وَقَصَّ عَلَيْهِ الْقَصَصَ قَالَ لَا تَخَفْ ۖ نَجَوْتَ مِنَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
Okan ninu awon mejeeji wa ba a, o si n rin pelu itiju, o so pe: “Dajudaju baba mi n pe o nitori ki o le san o ni esan omi ti o fun (awon eran-osin) wa mu.” Nigba ti o de odo re, o so itan (ara re) fun un. (Baba naa) so pe: “Ma beru. O ti la lowo ijo alabosi.”
قَالَتْ إِحْدَاهُمَا يَا أَبَتِ اسْتَأْجِرْهُ ۖ إِنَّ خَيْرَ مَنِ اسْتَأْجَرْتَ الْقَوِيُّ الْأَمِينُ
Okan ninu (awon omobinrin) mejeeji so pe: “Baba mi o, gba a sise. Dajudaju eni t’o dara julo ti o le gba sise ni alagbara, olufokantan.”
قَالَ إِنِّي أُرِيدُ أَنْ أُنْكِحَكَ إِحْدَى ابْنَتَيَّ هَاتَيْنِ عَلَىٰ أَنْ تَأْجُرَنِي ثَمَانِيَ حِجَجٍ ۖ فَإِنْ أَتْمَمْتَ عَشْرًا فَمِنْ عِنْدِكَ ۖ وَمَا أُرِيدُ أَنْ أَشُقَّ عَلَيْكَ ۚ سَتَجِدُنِي إِنْ شَاءَ اللَّهُ مِنَ الصَّالِحِينَ
O so pe: “Dajudaju mo fe fi okan ninu awon omobinrin mi mejeeji wonyi fun o ni aya lori (adehun) pe o maa ba mi sise fun odun mejo. Sugbon ti o ba se e pe odun mewaa, lati odo re niyen. Emi ko si fe ko inira ba o. Ti Allahu ba fe, o maa ri i pe mo wa ninu awon eni rere.”
قَالَ ذَٰلِكَ بَيْنِي وَبَيْنَكَ ۖ أَيَّمَا الْأَجَلَيْنِ قَضَيْتُ فَلَا عُدْوَانَ عَلَيَّ ۖ وَاللَّهُ عَلَىٰ مَا نَقُولُ وَكِيلٌ
(Musa) so pe: “(Adehun) yii wa laaarin emi ati iwo. Eyikeyii ti mo ba mu se ninu adehun mejeeji naa, iwo ko gbodo sabosi si mi. Allahu si ni Elerii lori ohun ti a n so (yii).”

Choose other languages: