Surah Al-Baqara Ayahs #148 Translated in Yoruba
قَدْ نَرَىٰ تَقَلُّبَ وَجْهِكَ فِي السَّمَاءِ ۖ فَلَنُوَلِّيَنَّكَ قِبْلَةً تَرْضَاهَا ۚ فَوَلِّ وَجْهَكَ شَطْرَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۚ وَحَيْثُ مَا كُنْتُمْ فَوَلُّوا وُجُوهَكُمْ شَطْرَهُ ۗ وَإِنَّ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ لَيَعْلَمُونَ أَنَّهُ الْحَقُّ مِنْ رَبِّهِمْ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا يَعْمَلُونَ
A kuku ri yiyi ti o n yi oju re si sanmo. Nitori naa, A o doju re ko Ƙiblah kan ti o yonu si; nitori naa, koju re si agbegbe Mosalasi Haram (ni Mokkah). Ibikibi ti e ba tun wa, e koju yin si agbegbe re. Dajudaju awon ti A fun ni Tira kuku mo pe dajudaju ododo ni (ase Ƙiblah) lati odo Oluwa won. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti won n se nise
وَلَئِنْ أَتَيْتَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ بِكُلِّ آيَةٍ مَا تَبِعُوا قِبْلَتَكَ ۚ وَمَا أَنْتَ بِتَابِعٍ قِبْلَتَهُمْ ۚ وَمَا بَعْضُهُمْ بِتَابِعٍ قِبْلَةَ بَعْضٍ ۚ وَلَئِنِ اتَّبَعْتَ أَهْوَاءَهُمْ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَكَ مِنَ الْعِلْمِ ۙ إِنَّكَ إِذًا لَمِنَ الظَّالِمِينَ
Dajudaju ti o ba fun awon ti A fun ni Tira ni gbogbo ayah, won ko nii tele Ƙiblah re. Iwo naa ko gbodo tele Ƙiblah won. Apa kan won ko si nii tele Ƙiblah apa kan. Dajudaju ti o ba tele ife-inu won leyin ohun ti o de ba o ninu imo, dajudaju nigba naa iwo wa ninu awon alabosi
الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ يَعْرِفُونَهُ كَمَا يَعْرِفُونَ أَبْنَاءَهُمْ ۖ وَإِنَّ فَرِيقًا مِنْهُمْ لَيَكْتُمُونَ الْحَقَّ وَهُمْ يَعْلَمُونَ
Awon ti A fun ni Tira, won mo Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) gege bi won se mo awon omo won. Dajudaju awon ijo kan wa ninu won ti won kuku n fi ododo pamo; won si mo
الْحَقُّ مِنْ رَبِّكَ ۖ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْمُمْتَرِينَ
Ododo naa wa lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo wa lara awon oniyemeji
وَلِكُلٍّ وِجْهَةٌ هُوَ مُوَلِّيهَا ۖ فَاسْتَبِقُوا الْخَيْرَاتِ ۚ أَيْنَ مَا تَكُونُوا يَأْتِ بِكُمُ اللَّهُ جَمِيعًا ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Ikookan (ijo elesin) l’o ni ibukojusi t’o n koju si. Nitori naa, e yara gbawaju nibi awon ise rere. Ibikibi ti e ba wa, Allahu yo mu gbogbo yin wa (ni Ojo Ajinde). Dajudaju Alagbara ni Allahu lori gbogbo nnkan
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
