Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #149 Translated in Yoruba

وَلَئِنْ أَتَيْتَ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ بِكُلِّ آيَةٍ مَا تَبِعُوا قِبْلَتَكَ ۚ وَمَا أَنْتَ بِتَابِعٍ قِبْلَتَهُمْ ۚ وَمَا بَعْضُهُمْ بِتَابِعٍ قِبْلَةَ بَعْضٍ ۚ وَلَئِنِ اتَّبَعْتَ أَهْوَاءَهُمْ مِنْ بَعْدِ مَا جَاءَكَ مِنَ الْعِلْمِ ۙ إِنَّكَ إِذًا لَمِنَ الظَّالِمِينَ
Dajudaju ti o ba fun awon ti A fun ni Tira ni gbogbo ayah, won ko nii tele Ƙiblah re. Iwo naa ko gbodo tele Ƙiblah won. Apa kan won ko si nii tele Ƙiblah apa kan. Dajudaju ti o ba tele ife-inu won leyin ohun ti o de ba o ninu imo, dajudaju nigba naa iwo wa ninu awon alabosi
الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ يَعْرِفُونَهُ كَمَا يَعْرِفُونَ أَبْنَاءَهُمْ ۖ وَإِنَّ فَرِيقًا مِنْهُمْ لَيَكْتُمُونَ الْحَقَّ وَهُمْ يَعْلَمُونَ
Awon ti A fun ni Tira, won mo Anabi (sollalahu alayhi wa sallam) gege bi won se mo awon omo won. Dajudaju awon ijo kan wa ninu won ti won kuku n fi ododo pamo; won si mo
الْحَقُّ مِنْ رَبِّكَ ۖ فَلَا تَكُونَنَّ مِنَ الْمُمْتَرِينَ
Ododo naa wa lati odo Oluwa re. Nitori naa, o o gbodo wa lara awon oniyemeji
وَلِكُلٍّ وِجْهَةٌ هُوَ مُوَلِّيهَا ۖ فَاسْتَبِقُوا الْخَيْرَاتِ ۚ أَيْنَ مَا تَكُونُوا يَأْتِ بِكُمُ اللَّهُ جَمِيعًا ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Ikookan (ijo elesin) l’o ni ibukojusi t’o n koju si. Nitori naa, e yara gbawaju nibi awon ise rere. Ibikibi ti e ba wa, Allahu yo mu gbogbo yin wa (ni Ojo Ajinde). Dajudaju Alagbara ni Allahu lori gbogbo nnkan
وَمِنْ حَيْثُ خَرَجْتَ فَوَلِّ وَجْهَكَ شَطْرَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۖ وَإِنَّهُ لَلْحَقُّ مِنْ رَبِّكَ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ
Ibikibi ti o ba jade lo, koju re si agbegbe Mosalasi Haram, nitori pe dajudaju ododo ni lati odo Oluwa re. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise

Choose other languages: