Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #120 Translated in Yoruba

وَقَالُوا اتَّخَذَ اللَّهُ وَلَدًا ۗ سُبْحَانَهُ ۖ بَلْ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ كُلٌّ لَهُ قَانِتُونَ
Won wi pe: “Allahu so eni kan di omo.” Mimo ni fun Un! Oro ko ri bee, (amo) tiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Eni kookan si ni olutele-ase Re
بَدِيعُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ وَإِذَا قَضَىٰ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُ كُنْ فَيَكُونُ
Olupileda awon sanmo ati ile ni (Allahu). Nigba ti O ba si pebubu kini kan, O kan maa so fun un pe: “Je bee.” O si maa je bee
وَقَالَ الَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ لَوْلَا يُكَلِّمُنَا اللَّهُ أَوْ تَأْتِينَا آيَةٌ ۗ كَذَٰلِكَ قَالَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ مِثْلَ قَوْلِهِمْ ۘ تَشَابَهَتْ قُلُوبُهُمْ ۗ قَدْ بَيَّنَّا الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يُوقِنُونَ
Awon ti ko nimo wi pe: “Ti o ba je pe Allahu n ba wa soro ni tabi ki ami kan wa ba wa (awa iba gbagbo)?” Bayen ni awon t’o siwaju won se so iru oro won (yii). Okan won jora won. A kuku ti se alaye awon ayah fun ijo to ni amodaju
إِنَّا أَرْسَلْنَاكَ بِالْحَقِّ بَشِيرًا وَنَذِيرًا ۖ وَلَا تُسْأَلُ عَنْ أَصْحَابِ الْجَحِيمِ
Dajudaju Awa fi ododo ran o nise. (O si je) oniroo-idunnu ati olukilo (fun gbogbo aye). Won ko si nii bi o leere nipa awon ero inu Ina
وَلَنْ تَرْضَىٰ عَنْكَ الْيَهُودُ وَلَا النَّصَارَىٰ حَتَّىٰ تَتَّبِعَ مِلَّتَهُمْ ۗ قُلْ إِنَّ هُدَى اللَّهِ هُوَ الْهُدَىٰ ۗ وَلَئِنِ اتَّبَعْتَ أَهْوَاءَهُمْ بَعْدَ الَّذِي جَاءَكَ مِنَ الْعِلْمِ ۙ مَا لَكَ مِنَ اللَّهِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Awon yehudi ati nasara ko nii yonu si o titi o fi maa tele esin won. So pe: “Dajudaju imona ti Allahu ni imona.” Dajudaju ti o ba si tele ife-inu won leyin eyi ti o de ba o ninu imo (’Islam), ko nii si alaabo ati alaranse kan fun o lodo Allahu

Choose other languages: