Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #165 Translated in Yoruba

وَإِذْ قِيلَ لَهُمُ اسْكُنُوا هَٰذِهِ الْقَرْيَةَ وَكُلُوا مِنْهَا حَيْثُ شِئْتُمْ وَقُولُوا حِطَّةٌ وَادْخُلُوا الْبَابَ سُجَّدًا نَغْفِرْ لَكُمْ خَطِيئَاتِكُمْ ۚ سَنَزِيدُ الْمُحْسِنِينَ
(E ranti) nigba ti A so fun won pe: “E wo inu ilu yii. E maa je ninu re nibikibi ti e ba fe. Ki e si so pe: ‘Ha ese wa danu.’ E gba enu-ona ilu wole ni oluteriba. A maa fori awon ese yin jin yin. A o si se alekun (esan rere) fun awon oluse-rere.”
فَبَدَّلَ الَّذِينَ ظَلَمُوا مِنْهُمْ قَوْلًا غَيْرَ الَّذِي قِيلَ لَهُمْ فَأَرْسَلْنَا عَلَيْهِمْ رِجْزًا مِنَ السَّمَاءِ بِمَا كَانُوا يَظْلِمُونَ
Awon t’o sabosi kuku yi oro naa pada si omiran ti o yato si eyi ti A so fun won. A si so iya kale lati sanmo le won lori nitori pe won n se abosi
وَاسْأَلْهُمْ عَنِ الْقَرْيَةِ الَّتِي كَانَتْ حَاضِرَةَ الْبَحْرِ إِذْ يَعْدُونَ فِي السَّبْتِ إِذْ تَأْتِيهِمْ حِيتَانُهُمْ يَوْمَ سَبْتِهِمْ شُرَّعًا وَيَوْمَ لَا يَسْبِتُونَ ۙ لَا تَأْتِيهِمْ ۚ كَذَٰلِكَ نَبْلُوهُمْ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ
Bi won leere nipa ilu t’o wa ni ebado, nigba ti won koja enu-ala nipa ojo Sabt, nigba ti eja won n wa ba won ni ojo Sabt won, won si maa lefoo si oju odo, ojo ti ki i ba si se ojo Sabt won, won ko nii wa ba won. Bayen ni A se n dan won wo nitori pe won je obileje
وَإِذْ قَالَتْ أُمَّةٌ مِنْهُمْ لِمَ تَعِظُونَ قَوْمًا ۙ اللَّهُ مُهْلِكُهُمْ أَوْ مُعَذِّبُهُمْ عَذَابًا شَدِيدًا ۖ قَالُوا مَعْذِرَةً إِلَىٰ رَبِّكُمْ وَلَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ
(Ranti) nigba ti ijo kan ninu won wi pe: “Nitori ki ni e fi n se waasi fun ijo kan ti Allahu maa pare tabi ti O maa je niya lile?” Won so pe: “(Ki o le je) awawi lodo Oluwa yin ati nitori ki won le beru (Allahu) ni.”
فَلَمَّا نَسُوا مَا ذُكِّرُوا بِهِ أَنْجَيْنَا الَّذِينَ يَنْهَوْنَ عَنِ السُّوءِ وَأَخَذْنَا الَّذِينَ ظَلَمُوا بِعَذَابٍ بَئِيسٍ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ
Nigba ti won si gbagbe ohun ti won fi seranti fun won, A gba awon t’o n ko aburu la. A si fi iya t’o le je awon t’o sabosi nitori pe won je obileje

Choose other languages: