Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #167 Translated in Yoruba

وَاسْأَلْهُمْ عَنِ الْقَرْيَةِ الَّتِي كَانَتْ حَاضِرَةَ الْبَحْرِ إِذْ يَعْدُونَ فِي السَّبْتِ إِذْ تَأْتِيهِمْ حِيتَانُهُمْ يَوْمَ سَبْتِهِمْ شُرَّعًا وَيَوْمَ لَا يَسْبِتُونَ ۙ لَا تَأْتِيهِمْ ۚ كَذَٰلِكَ نَبْلُوهُمْ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ
Bi won leere nipa ilu t’o wa ni ebado, nigba ti won koja enu-ala nipa ojo Sabt, nigba ti eja won n wa ba won ni ojo Sabt won, won si maa lefoo si oju odo, ojo ti ki i ba si se ojo Sabt won, won ko nii wa ba won. Bayen ni A se n dan won wo nitori pe won je obileje
وَإِذْ قَالَتْ أُمَّةٌ مِنْهُمْ لِمَ تَعِظُونَ قَوْمًا ۙ اللَّهُ مُهْلِكُهُمْ أَوْ مُعَذِّبُهُمْ عَذَابًا شَدِيدًا ۖ قَالُوا مَعْذِرَةً إِلَىٰ رَبِّكُمْ وَلَعَلَّهُمْ يَتَّقُونَ
(Ranti) nigba ti ijo kan ninu won wi pe: “Nitori ki ni e fi n se waasi fun ijo kan ti Allahu maa pare tabi ti O maa je niya lile?” Won so pe: “(Ki o le je) awawi lodo Oluwa yin ati nitori ki won le beru (Allahu) ni.”
فَلَمَّا نَسُوا مَا ذُكِّرُوا بِهِ أَنْجَيْنَا الَّذِينَ يَنْهَوْنَ عَنِ السُّوءِ وَأَخَذْنَا الَّذِينَ ظَلَمُوا بِعَذَابٍ بَئِيسٍ بِمَا كَانُوا يَفْسُقُونَ
Nigba ti won si gbagbe ohun ti won fi seranti fun won, A gba awon t’o n ko aburu la. A si fi iya t’o le je awon t’o sabosi nitori pe won je obileje
فَلَمَّا عَتَوْا عَنْ مَا نُهُوا عَنْهُ قُلْنَا لَهُمْ كُونُوا قِرَدَةً خَاسِئِينَ
Nigba ti won tayo enu-ala nibi ohun ti A ko fun won, A so fun won pe: “E di obo, eni igbejinna si ike.”
وَإِذْ تَأَذَّنَ رَبُّكَ لَيَبْعَثَنَّ عَلَيْهِمْ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ مَنْ يَسُومُهُمْ سُوءَ الْعَذَابِ ۗ إِنَّ رَبَّكَ لَسَرِيعُ الْعِقَابِ ۖ وَإِنَّهُ لَغَفُورٌ رَحِيمٌ
(Ranti) nigba ti Oluwa re so o di mimo pe dajudaju Oun yoo gbe eni ti o maa fi iya buruku je won dide si won titi di Ojo Ajinde. Dajudaju Oluwa re ni Oluyara nibi iya. Dajudaju Oun si ni Alaforijin, Asake-orun

Choose other languages: