Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahqaf Ayahs #14 Translated in Yoruba

قُلْ أَرَأَيْتُمْ إِنْ كَانَ مِنْ عِنْدِ اللَّهِ وَكَفَرْتُمْ بِهِ وَشَهِدَ شَاهِدٌ مِنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ عَلَىٰ مِثْلِهِ فَآمَنَ وَاسْتَكْبَرْتُمْ ۖ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
So pe: " E so fun mi, ti o ba je pe lati odo Allahu ni (al-Ƙur’an) ti wa, ti e si sai gbagbo ninu re, ti elerii kan ninu awon omo ’Isro’il si jerii lori iru re, ti o si gba a gbo, (amo) ti eyin segberaga si i, (se e o ti sabosi bayen bi?). Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi
وَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلَّذِينَ آمَنُوا لَوْ كَانَ خَيْرًا مَا سَبَقُونَا إِلَيْهِ ۚ وَإِذْ لَمْ يَهْتَدُوا بِهِ فَسَيَقُولُونَ هَٰذَا إِفْكٌ قَدِيمٌ
Awon t’o sai gbagbo wi fun awon t’o gbagbo pe: "Ti o ba je pe al-Ƙur’an je oore ni, won ko nii siwaju wa debe." Nigba ti awon osebo ko ti tele imona re, ni won n wi pe: "Iro ijoun ni eyi
وَمِنْ قَبْلِهِ كِتَابُ مُوسَىٰ إِمَامًا وَرَحْمَةً ۚ وَهَٰذَا كِتَابٌ مُصَدِّقٌ لِسَانًا عَرَبِيًّا لِيُنْذِرَ الَّذِينَ ظَلَمُوا وَبُشْرَىٰ لِلْمُحْسِنِينَ
Tira (Anabi) Musa si ti wa siwaju re, ti o je tira ti won n tele, o si je ike (fun won. Al-Ƙur’an) yii tun ni Tira kan t’o n jerii si ododo ni ede Larubawa nitori ki o le sekilo fun awon t’o sabosi, (o si je) iro idunnu fun awon oluse-rere
إِنَّ الَّذِينَ قَالُوا رَبُّنَا اللَّهُ ثُمَّ اسْتَقَامُوا فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Dajudaju awon t’o so pe: "Allahu ni Oluwa wa", leyin naa, ti won duro sinsin, ko nii si ipaya fun won. Won ko si nii banuje
أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ خَالِدِينَ فِيهَا جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re. (O je) esan nitori ohun ti won n se nise

Choose other languages: