Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahqaf Ayahs #16 Translated in Yoruba

وَمِنْ قَبْلِهِ كِتَابُ مُوسَىٰ إِمَامًا وَرَحْمَةً ۚ وَهَٰذَا كِتَابٌ مُصَدِّقٌ لِسَانًا عَرَبِيًّا لِيُنْذِرَ الَّذِينَ ظَلَمُوا وَبُشْرَىٰ لِلْمُحْسِنِينَ
Tira (Anabi) Musa si ti wa siwaju re, ti o je tira ti won n tele, o si je ike (fun won. Al-Ƙur’an) yii tun ni Tira kan t’o n jerii si ododo ni ede Larubawa nitori ki o le sekilo fun awon t’o sabosi, (o si je) iro idunnu fun awon oluse-rere
إِنَّ الَّذِينَ قَالُوا رَبُّنَا اللَّهُ ثُمَّ اسْتَقَامُوا فَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Dajudaju awon t’o so pe: "Allahu ni Oluwa wa", leyin naa, ti won duro sinsin, ko nii si ipaya fun won. Won ko si nii banuje
أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ خَالِدِينَ فِيهَا جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re. (O je) esan nitori ohun ti won n se nise
وَوَصَّيْنَا الْإِنْسَانَ بِوَالِدَيْهِ إِحْسَانًا ۖ حَمَلَتْهُ أُمُّهُ كُرْهًا وَوَضَعَتْهُ كُرْهًا ۖ وَحَمْلُهُ وَفِصَالُهُ ثَلَاثُونَ شَهْرًا ۚ حَتَّىٰ إِذَا بَلَغَ أَشُدَّهُ وَبَلَغَ أَرْبَعِينَ سَنَةً قَالَ رَبِّ أَوْزِعْنِي أَنْ أَشْكُرَ نِعْمَتَكَ الَّتِي أَنْعَمْتَ عَلَيَّ وَعَلَىٰ وَالِدَيَّ وَأَنْ أَعْمَلَ صَالِحًا تَرْضَاهُ وَأَصْلِحْ لِي فِي ذُرِّيَّتِي ۖ إِنِّي تُبْتُ إِلَيْكَ وَإِنِّي مِنَ الْمُسْلِمِينَ
A pa a ni ase fun eniyan pe ki o maa se daadaa si awon obi re mejeeji. Iya re ni oyun re pelu wahala. O si bi i pelu wahala. Oyun re ati gbigba omu lenu re je ogbon osu. (O si n to o) titi o fi dagba, ti o fi di omo ogoji odun, o si so pe: "Oluwa mi, fi mo mi ki ng maa dupe idera Re, eyi ti O fi se idera fun mi ati fun awon obi mi mejeeji, ki ng si maa se ise rere, eyi ti O yonu si. Ki O si se rere fun mi lori awon aromodomo mi. Dajudaju emi ti ronu piwada si odo Re. Dajudaju emi si wa ninu awon musulumi
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ نَتَقَبَّلُ عَنْهُمْ أَحْسَنَ مَا عَمِلُوا وَنَتَجَاوَزُ عَنْ سَيِّئَاتِهِمْ فِي أَصْحَابِ الْجَنَّةِ ۖ وَعْدَ الصِّدْقِ الَّذِي كَانُوا يُوعَدُونَ
Awon wonyen ni awon ti A maa gba ise rere ti won se nise, A si maa se amojukuro nibi awon aburu ise won; won maa wa ninu awon ero inu Ogba Idera. (O je) adehun ododo ti A n se ni adehun fun won

Choose other languages: