Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahqaf Ayahs #18 Translated in Yoruba

أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَنَّةِ خَالِدِينَ فِيهَا جَزَاءً بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Awon wonyen ni ero inu Ogba Idera. Olusegbere ni won ninu re. (O je) esan nitori ohun ti won n se nise
وَوَصَّيْنَا الْإِنْسَانَ بِوَالِدَيْهِ إِحْسَانًا ۖ حَمَلَتْهُ أُمُّهُ كُرْهًا وَوَضَعَتْهُ كُرْهًا ۖ وَحَمْلُهُ وَفِصَالُهُ ثَلَاثُونَ شَهْرًا ۚ حَتَّىٰ إِذَا بَلَغَ أَشُدَّهُ وَبَلَغَ أَرْبَعِينَ سَنَةً قَالَ رَبِّ أَوْزِعْنِي أَنْ أَشْكُرَ نِعْمَتَكَ الَّتِي أَنْعَمْتَ عَلَيَّ وَعَلَىٰ وَالِدَيَّ وَأَنْ أَعْمَلَ صَالِحًا تَرْضَاهُ وَأَصْلِحْ لِي فِي ذُرِّيَّتِي ۖ إِنِّي تُبْتُ إِلَيْكَ وَإِنِّي مِنَ الْمُسْلِمِينَ
A pa a ni ase fun eniyan pe ki o maa se daadaa si awon obi re mejeeji. Iya re ni oyun re pelu wahala. O si bi i pelu wahala. Oyun re ati gbigba omu lenu re je ogbon osu. (O si n to o) titi o fi dagba, ti o fi di omo ogoji odun, o si so pe: "Oluwa mi, fi mo mi ki ng maa dupe idera Re, eyi ti O fi se idera fun mi ati fun awon obi mi mejeeji, ki ng si maa se ise rere, eyi ti O yonu si. Ki O si se rere fun mi lori awon aromodomo mi. Dajudaju emi ti ronu piwada si odo Re. Dajudaju emi si wa ninu awon musulumi
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ نَتَقَبَّلُ عَنْهُمْ أَحْسَنَ مَا عَمِلُوا وَنَتَجَاوَزُ عَنْ سَيِّئَاتِهِمْ فِي أَصْحَابِ الْجَنَّةِ ۖ وَعْدَ الصِّدْقِ الَّذِي كَانُوا يُوعَدُونَ
Awon wonyen ni awon ti A maa gba ise rere ti won se nise, A si maa se amojukuro nibi awon aburu ise won; won maa wa ninu awon ero inu Ogba Idera. (O je) adehun ododo ti A n se ni adehun fun won
وَالَّذِي قَالَ لِوَالِدَيْهِ أُفٍّ لَكُمَا أَتَعِدَانِنِي أَنْ أُخْرَجَ وَقَدْ خَلَتِ الْقُرُونُ مِنْ قَبْلِي وَهُمَا يَسْتَغِيثَانِ اللَّهَ وَيْلَكَ آمِنْ إِنَّ وَعْدَ اللَّهِ حَقٌّ فَيَقُولُ مَا هَٰذَا إِلَّا أَسَاطِيرُ الْأَوَّلِينَ
Eni ti o so fun awon obi re mejeeji pe: "Sio eyin mejeeji! Se eyin yoo maa seleri fun mi pe Won yoo mu mi jade (laaye lati inu saree), sebi awon iran kan ti re koja lo siwaju mi (ti Won ko ti i mu won jade lati inu saree won)." Awon (obi re) mejeeji si n toro igbala ni odo Allahu (fun omo yii. Won si so pe): "Egbe ni fun o! (O je) gbagbo ni ododo. Dajudaju adehun Allahu ni ododo." (Omo naa si) wi pe: "Eyi ko je kini kan bi ko se akosile alo awon eni akoko
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ حَقَّ عَلَيْهِمُ الْقَوْلُ فِي أُمَمٍ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهِمْ مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنْسِ ۖ إِنَّهُمْ كَانُوا خَاسِرِينَ
Awon (alaigbagbo) wonyen ni awon ti oro naa ti ko le lori ninu awon ijo kan ti o ti re koja siwaju won ninu awon alujannu ati eniyan. Dajudaju won je eni ofo

Choose other languages: