Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rad Ayahs #30 Translated in Yoruba

اللَّهُ يَبْسُطُ الرِّزْقَ لِمَنْ يَشَاءُ وَيَقْدِرُ ۚ وَفَرِحُوا بِالْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَمَا الْحَيَاةُ الدُّنْيَا فِي الْآخِرَةِ إِلَّا مَتَاعٌ
Allahu n te arisiki sile regede fun eni ti O ba fe. O si n diwon re (fun eni ti O ba fe). Won si dunnu si isemi ile aye! Ki si ni isemi aye ni egbe ti orun bi ko se igbadun bin-intin
وَيَقُولُ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْهِ آيَةٌ مِنْ رَبِّهِ ۗ قُلْ إِنَّ اللَّهَ يُضِلُّ مَنْ يَشَاءُ وَيَهْدِي إِلَيْهِ مَنْ أَنَابَ
Awon t’o sai gbagbo n wi pe: “Ki ni ko je ki Won so ami kan kale fun un lati odo Oluwa re?” So pe: “Dajudaju Allahu n si eni ti O ba fe lona. O si n fi ona mo eni ti o ba seri sodo Re.”
الَّذِينَ آمَنُوا وَتَطْمَئِنُّ قُلُوبُهُمْ بِذِكْرِ اللَّهِ ۗ أَلَا بِذِكْرِ اللَّهِ تَطْمَئِنُّ الْقُلُوبُ
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti okan won si bale pelu iranti Allahu; e gbo, pelu iranti Allahu ni awon okan maa fi bale
الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ طُوبَىٰ لَهُمْ وَحُسْنُ مَآبٍ
Awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, ori ire ati abo rere wa fun won
كَذَٰلِكَ أَرْسَلْنَاكَ فِي أُمَّةٍ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهَا أُمَمٌ لِتَتْلُوَ عَلَيْهِمُ الَّذِي أَوْحَيْنَا إِلَيْكَ وَهُمْ يَكْفُرُونَ بِالرَّحْمَٰنِ ۚ قُلْ هُوَ رَبِّي لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ عَلَيْهِ تَوَكَّلْتُ وَإِلَيْهِ مَتَابِ
Bayen ni A se ran o nise si ijo kan, (eyi ti) awon ijo kan kuku ti re koja lo siwaju won, nitori ki o le maa ka fun won nnkan ti A fi ranse si o ni imisi. Sibesibe won n sai gbagbo ninu Ajoke-aye. So pe: “Oun ni Oluwa mi. Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Oun ni mo gbarale. Odo Re si ni abo mi.”

Choose other languages: