Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rad Ayahs #14 Translated in Yoruba

سَوَاءٌ مِنْكُمْ مَنْ أَسَرَّ الْقَوْلَ وَمَنْ جَهَرَ بِهِ وَمَنْ هُوَ مُسْتَخْفٍ بِاللَّيْلِ وَسَارِبٌ بِالنَّهَارِ
Bakan naa ni (lodo Allahu), eni ti o fi oro pamo sinu ninu yin ati eni ti o so o sita pelu eni ti o fi oru boju ati eni ti o n rin kiri ni osan
لَهُ مُعَقِّبَاتٌ مِنْ بَيْنِ يَدَيْهِ وَمِنْ خَلْفِهِ يَحْفَظُونَهُ مِنْ أَمْرِ اللَّهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يُغَيِّرُ مَا بِقَوْمٍ حَتَّىٰ يُغَيِّرُوا مَا بِأَنْفُسِهِمْ ۗ وَإِذَا أَرَادَ اللَّهُ بِقَوْمٍ سُوءًا فَلَا مَرَدَّ لَهُ ۚ وَمَا لَهُمْ مِنْ دُونِهِ مِنْ وَالٍ
O n be fun eniyan (kookan) awon molaika ti n gbase funra won; won wa niwaju (eniyan) ati leyin re; won n so (ise owo) re pelu ase Allahu. Dajudaju Allahu ko nii se iyipada nnkan t’o n be lodo ijo kan titi won yoo fi yi nnkan t’o n be ninu emi won pada. Nigba ti Allahu ba gbero aburu kan ro ijo kan, ko si eni t’o le da a pada. Ko si si alaabo kan fun won leyin Re
هُوَ الَّذِي يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنْشِئُ السَّحَابَ الثِّقَالَ
Oun ni Eni t’o n fi monamona han yin ni iberu ati ni ireti (fun yin). O si n seda esujo t’o su dede
وَيُسَبِّحُ الرَّعْدُ بِحَمْدِهِ وَالْمَلَائِكَةُ مِنْ خِيفَتِهِ وَيُرْسِلُ الصَّوَاعِقَ فَيُصِيبُ بِهَا مَنْ يَشَاءُ وَهُمْ يُجَادِلُونَ فِي اللَّهِ وَهُوَ شَدِيدُ الْمِحَالِ
Ara n se afomo ati idupe fun Un, awon molaika n se bee fun iberu Re. O n ran ina ara nise. O si n fi kolu eni ti O ba fe. Sibe won n jiyan nipa Allahu. O si le nibi gbigba-eda-mu
لَهُ دَعْوَةُ الْحَقِّ ۖ وَالَّذِينَ يَدْعُونَ مِنْ دُونِهِ لَا يَسْتَجِيبُونَ لَهُمْ بِشَيْءٍ إِلَّا كَبَاسِطِ كَفَّيْهِ إِلَى الْمَاءِ لِيَبْلُغَ فَاهُ وَمَا هُوَ بِبَالِغِهِ ۚ وَمَا دُعَاءُ الْكَافِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَالٍ
TiRe ni ipe ododo. Awon ti won n pe leyin Re, won ko le fi kini kan je pe won afi bi eni ti o tewo re mejeeji (lasan) si omi nitori ki omi le de enu re. Omi ko si le de enu re. Adua awon alaigbagbo ko si je kini kan bi ko se sinu isina

Choose other languages: