Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rad Ayahs #16 Translated in Yoruba

هُوَ الَّذِي يُرِيكُمُ الْبَرْقَ خَوْفًا وَطَمَعًا وَيُنْشِئُ السَّحَابَ الثِّقَالَ
Oun ni Eni t’o n fi monamona han yin ni iberu ati ni ireti (fun yin). O si n seda esujo t’o su dede
وَيُسَبِّحُ الرَّعْدُ بِحَمْدِهِ وَالْمَلَائِكَةُ مِنْ خِيفَتِهِ وَيُرْسِلُ الصَّوَاعِقَ فَيُصِيبُ بِهَا مَنْ يَشَاءُ وَهُمْ يُجَادِلُونَ فِي اللَّهِ وَهُوَ شَدِيدُ الْمِحَالِ
Ara n se afomo ati idupe fun Un, awon molaika n se bee fun iberu Re. O n ran ina ara nise. O si n fi kolu eni ti O ba fe. Sibe won n jiyan nipa Allahu. O si le nibi gbigba-eda-mu
لَهُ دَعْوَةُ الْحَقِّ ۖ وَالَّذِينَ يَدْعُونَ مِنْ دُونِهِ لَا يَسْتَجِيبُونَ لَهُمْ بِشَيْءٍ إِلَّا كَبَاسِطِ كَفَّيْهِ إِلَى الْمَاءِ لِيَبْلُغَ فَاهُ وَمَا هُوَ بِبَالِغِهِ ۚ وَمَا دُعَاءُ الْكَافِرِينَ إِلَّا فِي ضَلَالٍ
TiRe ni ipe ododo. Awon ti won n pe leyin Re, won ko le fi kini kan je pe won afi bi eni ti o tewo re mejeeji (lasan) si omi nitori ki omi le de enu re. Omi ko si le de enu re. Adua awon alaigbagbo ko si je kini kan bi ko se sinu isina
وَلِلَّهِ يَسْجُدُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ طَوْعًا وَكَرْهًا وَظِلَالُهُمْ بِالْغُدُوِّ وَالْآصَالِ ۩
Allahu ni awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile n fori kanle fun, won fe, won ko, - ooji won (naa n se bee) - ni owuro ati ni asale
قُلْ مَنْ رَبُّ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ قُلِ اللَّهُ ۚ قُلْ أَفَاتَّخَذْتُمْ مِنْ دُونِهِ أَوْلِيَاءَ لَا يَمْلِكُونَ لِأَنْفُسِهِمْ نَفْعًا وَلَا ضَرًّا ۚ قُلْ هَلْ يَسْتَوِي الْأَعْمَىٰ وَالْبَصِيرُ أَمْ هَلْ تَسْتَوِي الظُّلُمَاتُ وَالنُّورُ ۗ أَمْ جَعَلُوا لِلَّهِ شُرَكَاءَ خَلَقُوا كَخَلْقِهِ فَتَشَابَهَ الْخَلْقُ عَلَيْهِمْ ۚ قُلِ اللَّهُ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ وَهُوَ الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ
So pe: “Ta ni Oluwa awon sanmo ati ile?” So pe: “Allahu ni.” So pe: “Se leyin Re ni e tun mu awon alafeyinti kan, ti won ko ni ikapa oore ati inira fun emi ara won?” So pe: “Se afoju ati oluriran dogba bi? Tabi awon okunkun ati imole dogba? Tabi won yoo fun Allahu ni awon akegbe kan ti awon naa da eda bii ti eda Re, (to bee ge) ti eda fi jora won loju won?” So pe: “Allahu ni Eledaa gbogbo nnkan. Oun si ni Okan soso, Olubori

Choose other languages: