Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nur Ayahs #54 Translated in Yoruba

أَفِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ أَمِ ارْتَابُوا أَمْ يَخَافُونَ أَنْ يَحِيفَ اللَّهُ عَلَيْهِمْ وَرَسُولُهُ ۚ بَلْ أُولَٰئِكَ هُمُ الظَّالِمُونَ
Se arun wa ninu okan won ni tabi won seyemeji? Tabi won n paya pe Allahu ati Ojise Re yoo fi ejo won segbe ni? Rara o. Awon wonyen, awon ni alabosi
إِنَّمَا كَانَ قَوْلَ الْمُؤْمِنِينَ إِذَا دُعُوا إِلَى اللَّهِ وَرَسُولِهِ لِيَحْكُمَ بَيْنَهُمْ أَنْ يَقُولُوا سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا ۚ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُفْلِحُونَ
Ohun ti o maa je oro awon onigbagbo ododo nigba ti won ba pe won si ti Allahu ati ti Ojise Re nitori ki o le sedajo laaarin won, ni pe won a so pe: “A gbo (ase), a si tele (ase).” Awon wonyen, awon ni olujere
وَمَنْ يُطِعِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَيَخْشَ اللَّهَ وَيَتَّقْهِ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَائِزُونَ
Enikeni ti o ba tele ti Allahu ati ti Ojise Re, ti o n paya Allahu, ti o si n beru Re, awon wonyen, awon ni olujere
وَأَقْسَمُوا بِاللَّهِ جَهْدَ أَيْمَانِهِمْ لَئِنْ أَمَرْتَهُمْ لَيَخْرُجُنَّ ۖ قُلْ لَا تُقْسِمُوا ۖ طَاعَةٌ مَعْرُوفَةٌ ۚ إِنَّ اللَّهَ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ
Won si fi Allahu bura ti ibura won si ni agbara pe: "Dajudaju ti o ba pase fun awon, dajudaju awon yoo jade." So pe: “E ma se bura mo. Titele ase (pelu ibura iro enu yin) ti di ohun mimo (fun wa).” Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
قُلْ أَطِيعُوا اللَّهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ ۖ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَإِنَّمَا عَلَيْهِ مَا حُمِّلَ وَعَلَيْكُمْ مَا حُمِّلْتُمْ ۖ وَإِنْ تُطِيعُوهُ تَهْتَدُوا ۚ وَمَا عَلَى الرَّسُولِ إِلَّا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ
So pe: "E tele ti Allahu. Ki e si tele ti Ojise naa. Ti won ba peyin da, ohun ti A gbe ka a lorun l’o n be lorun re, ohun ti A si gbe ka yin lorun l’o n be lorun yin. Ti e ba si tele e, e maa mona taara. Ko si si ojuse kan fun Ojise bi ko se ise-jije ponnbele

Choose other languages: