Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nur Ayahs #57 Translated in Yoruba

وَأَقْسَمُوا بِاللَّهِ جَهْدَ أَيْمَانِهِمْ لَئِنْ أَمَرْتَهُمْ لَيَخْرُجُنَّ ۖ قُلْ لَا تُقْسِمُوا ۖ طَاعَةٌ مَعْرُوفَةٌ ۚ إِنَّ اللَّهَ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ
Won si fi Allahu bura ti ibura won si ni agbara pe: "Dajudaju ti o ba pase fun awon, dajudaju awon yoo jade." So pe: “E ma se bura mo. Titele ase (pelu ibura iro enu yin) ti di ohun mimo (fun wa).” Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
قُلْ أَطِيعُوا اللَّهَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ ۖ فَإِنْ تَوَلَّوْا فَإِنَّمَا عَلَيْهِ مَا حُمِّلَ وَعَلَيْكُمْ مَا حُمِّلْتُمْ ۖ وَإِنْ تُطِيعُوهُ تَهْتَدُوا ۚ وَمَا عَلَى الرَّسُولِ إِلَّا الْبَلَاغُ الْمُبِينُ
So pe: "E tele ti Allahu. Ki e si tele ti Ojise naa. Ti won ba peyin da, ohun ti A gbe ka a lorun l’o n be lorun re, ohun ti A si gbe ka yin lorun l’o n be lorun yin. Ti e ba si tele e, e maa mona taara. Ko si si ojuse kan fun Ojise bi ko se ise-jije ponnbele
وَعَدَ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا مِنْكُمْ وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ لَيَسْتَخْلِفَنَّهُمْ فِي الْأَرْضِ كَمَا اسْتَخْلَفَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ وَلَيُمَكِّنَنَّ لَهُمْ دِينَهُمُ الَّذِي ارْتَضَىٰ لَهُمْ وَلَيُبَدِّلَنَّهُمْ مِنْ بَعْدِ خَوْفِهِمْ أَمْنًا ۚ يَعْبُدُونَنِي لَا يُشْرِكُونَ بِي شَيْئًا ۚ وَمَنْ كَفَرَ بَعْدَ ذَٰلِكَ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْفَاسِقُونَ
Allahu sadehun fun awon t’o gbagbo ni ododo ninu yin, ti won si se awon ise rere pe dajudaju O maa fi won se arole lori ile gege bi O se fi awon t’o siwaju won se arole. Dajudaju O maa fi aye gba esin won fun won, eyi ti O yonu si fun won. Leyin iberu won, dajudaju O maa fi ifayabale dipo re fun won. Won n josin fun Mi, won ko si fi nnkan kan sebo si Mi. Enikeni ti o ba si sai moore leyin iyen, awon wonyen, awon ni obileje
وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ
E kirun. E yo Zakah. E tele Ojise naa nitori ki A le ke yin
لَا تَحْسَبَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مُعْجِزِينَ فِي الْأَرْضِ ۚ وَمَأْوَاهُمُ النَّارُ ۖ وَلَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Ma se lero pe awon t’o sai gbagbo mori bo ninu iya lori ile. Ina ni ibugbe won. Ikangun naa si buru

Choose other languages: