Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nur Ayahs #60 Translated in Yoruba

وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ وَأَطِيعُوا الرَّسُولَ لَعَلَّكُمْ تُرْحَمُونَ
E kirun. E yo Zakah. E tele Ojise naa nitori ki A le ke yin
لَا تَحْسَبَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مُعْجِزِينَ فِي الْأَرْضِ ۚ وَمَأْوَاهُمُ النَّارُ ۖ وَلَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Ma se lero pe awon t’o sai gbagbo mori bo ninu iya lori ile. Ina ni ibugbe won. Ikangun naa si buru
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لِيَسْتَأْذِنْكُمُ الَّذِينَ مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ وَالَّذِينَ لَمْ يَبْلُغُوا الْحُلُمَ مِنْكُمْ ثَلَاثَ مَرَّاتٍ ۚ مِنْ قَبْلِ صَلَاةِ الْفَجْرِ وَحِينَ تَضَعُونَ ثِيَابَكُمْ مِنَ الظَّهِيرَةِ وَمِنْ بَعْدِ صَلَاةِ الْعِشَاءِ ۚ ثَلَاثُ عَوْرَاتٍ لَكُمْ ۚ لَيْسَ عَلَيْكُمْ وَلَا عَلَيْهِمْ جُنَاحٌ بَعْدَهُنَّ ۚ طَوَّافُونَ عَلَيْكُمْ بَعْضُكُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ki awon eru yin ati awon ti ko ti i balaga ninu yin maa gba iyonda lodo yin nigba meta (wonyi): siwaju irun Subh, nigba ti e ba n bo aso yin sile fun oorun osan ati leyin irun ale. (Igba) meta fun iborasile yin (niyi). Ko si ese fun eyin ati awon leyin (asiko) naa pe ki won wole to yin; ki apa kan yin wole to apa kan. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah naa fun yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon
وَإِذَا بَلَغَ الْأَطْفَالُ مِنْكُمُ الْحُلُمَ فَلْيَسْتَأْذِنُوا كَمَا اسْتَأْذَنَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمْ آيَاتِهِ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Nigba ti awon omode yin ba si balaga, ki awon naa maa gba iyonda gege bi awon t’o siwaju won se gba iyonda. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah Re fun yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon
وَالْقَوَاعِدُ مِنَ النِّسَاءِ اللَّاتِي لَا يَرْجُونَ نِكَاحًا فَلَيْسَ عَلَيْهِنَّ جُنَاحٌ أَنْ يَضَعْنَ ثِيَابَهُنَّ غَيْرَ مُتَبَرِّجَاتٍ بِزِينَةٍ ۖ وَأَنْ يَسْتَعْفِفْنَ خَيْرٌ لَهُنَّ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Awon t’o ti dagba koja omo bibi ninu awon obinrin, awon ti ko reti ibalopo oorun ife mo, ko si ese fun won lati bo awon aso jilbab won sile, ti won ko si nii se afihan oso kan sita. Ki won si maa wo aso jilbab won lo bee loore julo fun won. Allahu si ni Olugbo, Onimo

Choose other languages: