Surah An-Nur Ayahs #61 Translated in Yoruba
لَا تَحْسَبَنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا مُعْجِزِينَ فِي الْأَرْضِ ۚ وَمَأْوَاهُمُ النَّارُ ۖ وَلَبِئْسَ الْمَصِيرُ
Ma se lero pe awon t’o sai gbagbo mori bo ninu iya lori ile. Ina ni ibugbe won. Ikangun naa si buru
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لِيَسْتَأْذِنْكُمُ الَّذِينَ مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ وَالَّذِينَ لَمْ يَبْلُغُوا الْحُلُمَ مِنْكُمْ ثَلَاثَ مَرَّاتٍ ۚ مِنْ قَبْلِ صَلَاةِ الْفَجْرِ وَحِينَ تَضَعُونَ ثِيَابَكُمْ مِنَ الظَّهِيرَةِ وَمِنْ بَعْدِ صَلَاةِ الْعِشَاءِ ۚ ثَلَاثُ عَوْرَاتٍ لَكُمْ ۚ لَيْسَ عَلَيْكُمْ وَلَا عَلَيْهِمْ جُنَاحٌ بَعْدَهُنَّ ۚ طَوَّافُونَ عَلَيْكُمْ بَعْضُكُمْ عَلَىٰ بَعْضٍ ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, ki awon eru yin ati awon ti ko ti i balaga ninu yin maa gba iyonda lodo yin nigba meta (wonyi): siwaju irun Subh, nigba ti e ba n bo aso yin sile fun oorun osan ati leyin irun ale. (Igba) meta fun iborasile yin (niyi). Ko si ese fun eyin ati awon leyin (asiko) naa pe ki won wole to yin; ki apa kan yin wole to apa kan. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah naa fun yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon
وَإِذَا بَلَغَ الْأَطْفَالُ مِنْكُمُ الْحُلُمَ فَلْيَسْتَأْذِنُوا كَمَا اسْتَأْذَنَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمْ آيَاتِهِ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ حَكِيمٌ
Nigba ti awon omode yin ba si balaga, ki awon naa maa gba iyonda gege bi awon t’o siwaju won se gba iyonda. Bayen ni Allahu se n se alaye awon ayah Re fun yin. Allahu si ni Onimo, Ologbon
وَالْقَوَاعِدُ مِنَ النِّسَاءِ اللَّاتِي لَا يَرْجُونَ نِكَاحًا فَلَيْسَ عَلَيْهِنَّ جُنَاحٌ أَنْ يَضَعْنَ ثِيَابَهُنَّ غَيْرَ مُتَبَرِّجَاتٍ بِزِينَةٍ ۖ وَأَنْ يَسْتَعْفِفْنَ خَيْرٌ لَهُنَّ ۗ وَاللَّهُ سَمِيعٌ عَلِيمٌ
Awon t’o ti dagba koja omo bibi ninu awon obinrin, awon ti ko reti ibalopo oorun ife mo, ko si ese fun won lati bo awon aso jilbab won sile, ti won ko si nii se afihan oso kan sita. Ki won si maa wo aso jilbab won lo bee loore julo fun won. Allahu si ni Olugbo, Onimo
لَيْسَ عَلَى الْأَعْمَىٰ حَرَجٌ وَلَا عَلَى الْأَعْرَجِ حَرَجٌ وَلَا عَلَى الْمَرِيضِ حَرَجٌ وَلَا عَلَىٰ أَنْفُسِكُمْ أَنْ تَأْكُلُوا مِنْ بُيُوتِكُمْ أَوْ بُيُوتِ آبَائِكُمْ أَوْ بُيُوتِ أُمَّهَاتِكُمْ أَوْ بُيُوتِ إِخْوَانِكُمْ أَوْ بُيُوتِ أَخَوَاتِكُمْ أَوْ بُيُوتِ أَعْمَامِكُمْ أَوْ بُيُوتِ عَمَّاتِكُمْ أَوْ بُيُوتِ أَخْوَالِكُمْ أَوْ بُيُوتِ خَالَاتِكُمْ أَوْ مَا مَلَكْتُمْ مَفَاتِحَهُ أَوْ صَدِيقِكُمْ ۚ لَيْسَ عَلَيْكُمْ جُنَاحٌ أَنْ تَأْكُلُوا جَمِيعًا أَوْ أَشْتَاتًا ۚ فَإِذَا دَخَلْتُمْ بُيُوتًا فَسَلِّمُوا عَلَىٰ أَنْفُسِكُمْ تَحِيَّةً مِنْ عِنْدِ اللَّهِ مُبَارَكَةً طَيِّبَةً ۚ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ لَعَلَّكُمْ تَعْقِلُونَ
Ko si ese fun afoju, ko si ese fun aro, ko si ese fun alaisan, ko si si ese fun eyin naa lati jeun ninu ile yin, tabi ile awon baba yin, tabi ile awon iya yin, tabi ile awon arakunrin yin, tabi ile awon arabinrin yin, tabi ile awon arakunrin baba yin, tabi ile awon arabinrin baba yin, tabi ile awon arakunrin iya yin, tabi ile awon arabinrin iya yin, tabi (ile) ti e ni ikapa lori kokoro re, tabi (ile) ore yin. Ko si ese fun yin lati jeun papo tabi ni otooto. Nitori naa, ti e ba wo awon inu ile kan, e salamo sira yin. (Eyi je) ikini ibukun t’o dara lati odo Allahu. Bayen ni Allahu se n salaye awon ayah naa fun yin nitori ki e le se laakaye
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
