Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #18 Translated in Yoruba

وَمَنْ يَعْصِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَيَتَعَدَّ حُدُودَهُ يُدْخِلْهُ نَارًا خَالِدًا فِيهَا وَلَهُ عَذَابٌ مُهِينٌ
Enikeni ti o ba si yapa (ase) Allahu ati Ojise Re, ti o si n tayo awon enu-ala ti Allahu gbekale, (Allahu) yoo mu un wo inu Ina kan. Olusegbere ni ninu re. Iya ti i yepere eda si n be fun un
وَاللَّاتِي يَأْتِينَ الْفَاحِشَةَ مِنْ نِسَائِكُمْ فَاسْتَشْهِدُوا عَلَيْهِنَّ أَرْبَعَةً مِنْكُمْ ۖ فَإِنْ شَهِدُوا فَأَمْسِكُوهُنَّ فِي الْبُيُوتِ حَتَّىٰ يَتَوَفَّاهُنَّ الْمَوْتُ أَوْ يَجْعَلَ اللَّهُ لَهُنَّ سَبِيلًا
Awon t’o n se sina ninu awon obinrin yin, e wa elerii merin ninu yin ti o maa jerii le won lori. Ti won ba jerii le won lori, ki e de won mo inu ile titi iku yoo fi pa won tabi (titi) Allahu yoo fi fun won ni ona (miiran)
وَاللَّذَانِ يَأْتِيَانِهَا مِنْكُمْ فَآذُوهُمَا ۖ فَإِنْ تَابَا وَأَصْلَحَا فَأَعْرِضُوا عَنْهُمَا ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ تَوَّابًا رَحِيمًا
Awon meji ti won se (sina) ninu yin, ki e (fenu) ba won wi. Ti won ba si ronu piwada, ti won satunse, ki e moju kuro lara won. Dajudaju Allahu n je Olugba-ironupiwada, Asake-orun
إِنَّمَا التَّوْبَةُ عَلَى اللَّهِ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ السُّوءَ بِجَهَالَةٍ ثُمَّ يَتُوبُونَ مِنْ قَرِيبٍ فَأُولَٰئِكَ يَتُوبُ اللَّهُ عَلَيْهِمْ ۗ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا
Ironupiwada ti Allahu yoo gba ni ti awon t’o n se ise aburu pelu aimokan. Leyin naa, won ronu piwada laipe. Awon wonyi ni Allahu yoo gba ironupiwada won. Allahu si n je Onimo, Ologbon
وَلَيْسَتِ التَّوْبَةُ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ السَّيِّئَاتِ حَتَّىٰ إِذَا حَضَرَ أَحَدَهُمُ الْمَوْتُ قَالَ إِنِّي تُبْتُ الْآنَ وَلَا الَّذِينَ يَمُوتُونَ وَهُمْ كُفَّارٌ ۚ أُولَٰئِكَ أَعْتَدْنَا لَهُمْ عَذَابًا أَلِيمًا
Ko si ironupiwada fun awon t’o n se aburu titi iku fi de ba okan ninu won, ki o wa wi pe: “Dajudaju emi ronu piwada nisinsin yii.” (Ko tun si ironupiwada) fun awon t’o ku sipo alaigbagbo. Awon wonyen, A ti pese iya eleta elero sile de won

Choose other languages: