Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #17 Translated in Yoruba

تِلْكَ حُدُودُ اللَّهِ ۚ وَمَنْ يُطِعِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ يُدْخِلْهُ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ خَالِدِينَ فِيهَا ۚ وَذَٰلِكَ الْفَوْزُ الْعَظِيمُ
Iyen ni awon enu-ala (ti) Allahu (gbekale fun ogun pipin). Enikeni ti o ba si tele ti Allahu ati Ojise Re, (Allahu) yoo mu un wo inu awon Ogba Idera kan ti awon odo n san ni isale re. Olusegbere ni won ninu re. Iyen si ni erenje nla
وَمَنْ يَعْصِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ وَيَتَعَدَّ حُدُودَهُ يُدْخِلْهُ نَارًا خَالِدًا فِيهَا وَلَهُ عَذَابٌ مُهِينٌ
Enikeni ti o ba si yapa (ase) Allahu ati Ojise Re, ti o si n tayo awon enu-ala ti Allahu gbekale, (Allahu) yoo mu un wo inu Ina kan. Olusegbere ni ninu re. Iya ti i yepere eda si n be fun un
وَاللَّاتِي يَأْتِينَ الْفَاحِشَةَ مِنْ نِسَائِكُمْ فَاسْتَشْهِدُوا عَلَيْهِنَّ أَرْبَعَةً مِنْكُمْ ۖ فَإِنْ شَهِدُوا فَأَمْسِكُوهُنَّ فِي الْبُيُوتِ حَتَّىٰ يَتَوَفَّاهُنَّ الْمَوْتُ أَوْ يَجْعَلَ اللَّهُ لَهُنَّ سَبِيلًا
Awon t’o n se sina ninu awon obinrin yin, e wa elerii merin ninu yin ti o maa jerii le won lori. Ti won ba jerii le won lori, ki e de won mo inu ile titi iku yoo fi pa won tabi (titi) Allahu yoo fi fun won ni ona (miiran)
وَاللَّذَانِ يَأْتِيَانِهَا مِنْكُمْ فَآذُوهُمَا ۖ فَإِنْ تَابَا وَأَصْلَحَا فَأَعْرِضُوا عَنْهُمَا ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ تَوَّابًا رَحِيمًا
Awon meji ti won se (sina) ninu yin, ki e (fenu) ba won wi. Ti won ba si ronu piwada, ti won satunse, ki e moju kuro lara won. Dajudaju Allahu n je Olugba-ironupiwada, Asake-orun
إِنَّمَا التَّوْبَةُ عَلَى اللَّهِ لِلَّذِينَ يَعْمَلُونَ السُّوءَ بِجَهَالَةٍ ثُمَّ يَتُوبُونَ مِنْ قَرِيبٍ فَأُولَٰئِكَ يَتُوبُ اللَّهُ عَلَيْهِمْ ۗ وَكَانَ اللَّهُ عَلِيمًا حَكِيمًا
Ironupiwada ti Allahu yoo gba ni ti awon t’o n se ise aburu pelu aimokan. Leyin naa, won ronu piwada laipe. Awon wonyi ni Allahu yoo gba ironupiwada won. Allahu si n je Onimo, Ologbon

Choose other languages: