Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #31 Translated in Yoruba

وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ ابْنَيْ آدَمَ بِالْحَقِّ إِذْ قَرَّبَا قُرْبَانًا فَتُقُبِّلَ مِنْ أَحَدِهِمَا وَلَمْ يُتَقَبَّلْ مِنَ الْآخَرِ قَالَ لَأَقْتُلَنَّكَ ۖ قَالَ إِنَّمَا يَتَقَبَّلُ اللَّهُ مِنَ الْمُتَّقِينَ
Ka oro awon omo (Anabi) Adam mejeeji fun won pelu ododo. (Ranti) nigba ti awon mejeeji se itore ase (lati fi sunmo Allahu). Won gba ti okan ninu awon mejeeji, Won ko si gba ti ikeji. (Eni ti Won ko gba tire) wi pe: “Dajudaju emi yoo pa o.” (Ikeji) si so pe: "(Ore) tawon oluberu nikan ni Allahu maa gba
لَئِنْ بَسَطْتَ إِلَيَّ يَدَكَ لِتَقْتُلَنِي مَا أَنَا بِبَاسِطٍ يَدِيَ إِلَيْكَ لِأَقْتُلَكَ ۖ إِنِّي أَخَافُ اللَّهَ رَبَّ الْعَالَمِينَ
Dajudaju ti o ba na owo re si mi lati pa mi, emi ko si nii na owo mi si o lati pa o, nitori pe emi n beru Allahu, Oluwa gbogbo eda
إِنِّي أُرِيدُ أَنْ تَبُوءَ بِإِثْمِي وَإِثْمِكَ فَتَكُونَ مِنْ أَصْحَابِ النَّارِ ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ الظَّالِمِينَ
Dajudaju emi fe ki o pada (si odo Allahu ni Ojo Ajinde) pelu ese (bi o se pa) mi ati ese tire nitori ki o le je okan ninu awon ero inu Ina. Iyen si ni esan awon alabosi
فَطَوَّعَتْ لَهُ نَفْسُهُ قَتْلَ أَخِيهِ فَقَتَلَهُ فَأَصْبَحَ مِنَ الْخَاسِرِينَ
Emi re si gba fun un lati pa arakunrin re. O pa a. O si di okan ninu awon eni ofo
فَبَعَثَ اللَّهُ غُرَابًا يَبْحَثُ فِي الْأَرْضِ لِيُرِيَهُ كَيْفَ يُوَارِي سَوْءَةَ أَخِيهِ ۚ قَالَ يَا وَيْلَتَا أَعَجَزْتُ أَنْ أَكُونَ مِثْلَ هَٰذَا الْغُرَابِ فَأُوَارِيَ سَوْءَةَ أَخِي ۖ فَأَصْبَحَ مِنَ النَّادِمِينَ
Allahu si gbe eye kannakanna kan dide. O si n fi ese wa ile nitori ki o le fi bi o se maa bo oku arakunrin re mo inu ile han an. O wi pe: “Temi baje o! Mo kagara lati da bi iru eye kannakanna yii, ki ng si le bo oku arakunrin mi mole.” O si di ara awon alabaamo

Choose other languages: