Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #32 Translated in Yoruba

لَئِنْ بَسَطْتَ إِلَيَّ يَدَكَ لِتَقْتُلَنِي مَا أَنَا بِبَاسِطٍ يَدِيَ إِلَيْكَ لِأَقْتُلَكَ ۖ إِنِّي أَخَافُ اللَّهَ رَبَّ الْعَالَمِينَ
Dajudaju ti o ba na owo re si mi lati pa mi, emi ko si nii na owo mi si o lati pa o, nitori pe emi n beru Allahu, Oluwa gbogbo eda
إِنِّي أُرِيدُ أَنْ تَبُوءَ بِإِثْمِي وَإِثْمِكَ فَتَكُونَ مِنْ أَصْحَابِ النَّارِ ۚ وَذَٰلِكَ جَزَاءُ الظَّالِمِينَ
Dajudaju emi fe ki o pada (si odo Allahu ni Ojo Ajinde) pelu ese (bi o se pa) mi ati ese tire nitori ki o le je okan ninu awon ero inu Ina. Iyen si ni esan awon alabosi
فَطَوَّعَتْ لَهُ نَفْسُهُ قَتْلَ أَخِيهِ فَقَتَلَهُ فَأَصْبَحَ مِنَ الْخَاسِرِينَ
Emi re si gba fun un lati pa arakunrin re. O pa a. O si di okan ninu awon eni ofo
فَبَعَثَ اللَّهُ غُرَابًا يَبْحَثُ فِي الْأَرْضِ لِيُرِيَهُ كَيْفَ يُوَارِي سَوْءَةَ أَخِيهِ ۚ قَالَ يَا وَيْلَتَا أَعَجَزْتُ أَنْ أَكُونَ مِثْلَ هَٰذَا الْغُرَابِ فَأُوَارِيَ سَوْءَةَ أَخِي ۖ فَأَصْبَحَ مِنَ النَّادِمِينَ
Allahu si gbe eye kannakanna kan dide. O si n fi ese wa ile nitori ki o le fi bi o se maa bo oku arakunrin re mo inu ile han an. O wi pe: “Temi baje o! Mo kagara lati da bi iru eye kannakanna yii, ki ng si le bo oku arakunrin mi mole.” O si di ara awon alabaamo
مِنْ أَجْلِ ذَٰلِكَ كَتَبْنَا عَلَىٰ بَنِي إِسْرَائِيلَ أَنَّهُ مَنْ قَتَلَ نَفْسًا بِغَيْرِ نَفْسٍ أَوْ فَسَادٍ فِي الْأَرْضِ فَكَأَنَّمَا قَتَلَ النَّاسَ جَمِيعًا وَمَنْ أَحْيَاهَا فَكَأَنَّمَا أَحْيَا النَّاسَ جَمِيعًا ۚ وَلَقَدْ جَاءَتْهُمْ رُسُلُنَا بِالْبَيِّنَاتِ ثُمَّ إِنَّ كَثِيرًا مِنْهُمْ بَعْدَ ذَٰلِكَ فِي الْأَرْضِ لَمُسْرِفُونَ
Nitori iyen, A si se e ni ofin fun awon omo ’Isro’il pe dajudaju enikeni ti o ba pa emi (eniyan) kan laije nitori pipa emi (eniyan) kan tabi sise ibaje kan lori ile, o da bi eni ti o pa gbogbo eniyan patapata. Enikeni ti o ba si mu emi (eniyan) semi, o da bi eni ti o mu gbogbo eniyan semi patapata. Awon Ojise Wa si ti wa ba won pelu awon eri t’o yanju. Leyin naa, dajudaju opolopo ninu won leyin iyen ni alakoyo lori ile

Choose other languages: