Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Fath Ayahs #15 Translated in Yoruba

سَيَقُولُ لَكَ الْمُخَلَّفُونَ مِنَ الْأَعْرَابِ شَغَلَتْنَا أَمْوَالُنَا وَأَهْلُونَا فَاسْتَغْفِرْ لَنَا ۚ يَقُولُونَ بِأَلْسِنَتِهِمْ مَا لَيْسَ فِي قُلُوبِهِمْ ۚ قُلْ فَمَنْ يَمْلِكُ لَكُمْ مِنَ اللَّهِ شَيْئًا إِنْ أَرَادَ بِكُمْ ضَرًّا أَوْ أَرَادَ بِكُمْ نَفْعًا ۚ بَلْ كَانَ اللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا
Awon olusaseyin fun ogun esin ninu awon Larubawa oko yoo maa wi fun o pe: "Awon dukia wa ati awon ara ile wa l’o ko airoju ba wa. Nitori naa, toro aforijin fun wa." Won n fi ahon won wi ohun ti ko si ninu okan won. So pe: "Ta ni o ni ikapa kini kan fun yin lodo Allahu ti O ba gbero (lati fi) inira kan yin tabi ti O ba gbero anfaani kan fun yin? Rara (ko si). Allahu n je Alamotan nipa ohun ti e n se nise
بَلْ ظَنَنْتُمْ أَنْ لَنْ يَنْقَلِبَ الرَّسُولُ وَالْمُؤْمِنُونَ إِلَىٰ أَهْلِيهِمْ أَبَدًا وَزُيِّنَ ذَٰلِكَ فِي قُلُوبِكُمْ وَظَنَنْتُمْ ظَنَّ السَّوْءِ وَكُنْتُمْ قَوْمًا بُورًا
Rara (ki i se ise kan l’o di yin lowo lati lo jagun, amo) e ti lero pe Ojise ati awon onigbagbo ododo ko nii pada si odo ara ile won mo laelae. Won se iyen ni oso sinu okan yin. E si ro ero aburu. E si je ijo iparun
وَمَنْ لَمْ يُؤْمِنْ بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ فَإِنَّا أَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ سَعِيرًا
Enikeni ti ko ba gba Allahu ati Ojise Re gbo, dajudaju Awa pese Ina sile de awon alaigbagbo
وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ يَغْفِرُ لِمَنْ يَشَاءُ وَيُعَذِّبُ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَحِيمًا
Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. O n saforijin fun eni ti O ba fe. O si n je eni ti O ba fe niya. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun
سَيَقُولُ الْمُخَلَّفُونَ إِذَا انْطَلَقْتُمْ إِلَىٰ مَغَانِمَ لِتَأْخُذُوهَا ذَرُونَا نَتَّبِعْكُمْ ۖ يُرِيدُونَ أَنْ يُبَدِّلُوا كَلَامَ اللَّهِ ۚ قُلْ لَنْ تَتَّبِعُونَا كَذَٰلِكُمْ قَالَ اللَّهُ مِنْ قَبْلُ ۖ فَسَيَقُولُونَ بَلْ تَحْسُدُونَنَا ۚ بَلْ كَانُوا لَا يَفْقَهُونَ إِلَّا قَلِيلًا
Awon olusaseyin fun ogun (Hudaebiyyah) n wi pe: "Nigba ti e lo sibi oro-ogun (Kaebar) nitori ki e le ri nnkan ko, won ja wa ju sile ki a ma le tele yin lo." (Awon olusaseyin wonyi) si n gbero lati yi oro Allahu pada ni. (Iwo Anabi) so pe: "Eyin ko gbodo tele wa. Bayen ni Allahu se so teletele." Won yo si tun wi pe: "Rara (ko ri bee), e n se keeta wa ni." Rara (eyin ko se keeta won, amo), won ki i gbo agboye (oro) afi die

Choose other languages: