Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Fath Ayahs #17 Translated in Yoruba

وَمَنْ لَمْ يُؤْمِنْ بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ فَإِنَّا أَعْتَدْنَا لِلْكَافِرِينَ سَعِيرًا
Enikeni ti ko ba gba Allahu ati Ojise Re gbo, dajudaju Awa pese Ina sile de awon alaigbagbo
وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ يَغْفِرُ لِمَنْ يَشَاءُ وَيُعَذِّبُ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَحِيمًا
Ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile. O n saforijin fun eni ti O ba fe. O si n je eni ti O ba fe niya. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun
سَيَقُولُ الْمُخَلَّفُونَ إِذَا انْطَلَقْتُمْ إِلَىٰ مَغَانِمَ لِتَأْخُذُوهَا ذَرُونَا نَتَّبِعْكُمْ ۖ يُرِيدُونَ أَنْ يُبَدِّلُوا كَلَامَ اللَّهِ ۚ قُلْ لَنْ تَتَّبِعُونَا كَذَٰلِكُمْ قَالَ اللَّهُ مِنْ قَبْلُ ۖ فَسَيَقُولُونَ بَلْ تَحْسُدُونَنَا ۚ بَلْ كَانُوا لَا يَفْقَهُونَ إِلَّا قَلِيلًا
Awon olusaseyin fun ogun (Hudaebiyyah) n wi pe: "Nigba ti e lo sibi oro-ogun (Kaebar) nitori ki e le ri nnkan ko, won ja wa ju sile ki a ma le tele yin lo." (Awon olusaseyin wonyi) si n gbero lati yi oro Allahu pada ni. (Iwo Anabi) so pe: "Eyin ko gbodo tele wa. Bayen ni Allahu se so teletele." Won yo si tun wi pe: "Rara (ko ri bee), e n se keeta wa ni." Rara (eyin ko se keeta won, amo), won ki i gbo agboye (oro) afi die
قُلْ لِلْمُخَلَّفِينَ مِنَ الْأَعْرَابِ سَتُدْعَوْنَ إِلَىٰ قَوْمٍ أُولِي بَأْسٍ شَدِيدٍ تُقَاتِلُونَهُمْ أَوْ يُسْلِمُونَ ۖ فَإِنْ تُطِيعُوا يُؤْتِكُمُ اللَّهُ أَجْرًا حَسَنًا ۖ وَإِنْ تَتَوَلَّوْا كَمَا تَوَلَّيْتُمْ مِنْ قَبْلُ يُعَذِّبْكُمْ عَذَابًا أَلِيمًا
So fun awon olusaseyin fun ogun ninu awon Larubawa oko pe: "Won maa pe yin si awon eniyan kan ti won ni agbara ogun jija. E maa ja won logun tabi ki won juwo juse sile (fun ’Islam). Ti eyin ba tele ase (yii), Allahu yoo fun yin ni esan t’o dara. Ti eyin ba si gbunri pada gege bi e se gbunri siwaju, (Allahu) yo si fi iya eleta-elero je yin
لَيْسَ عَلَى الْأَعْمَىٰ حَرَجٌ وَلَا عَلَى الْأَعْرَجِ حَرَجٌ وَلَا عَلَى الْمَرِيضِ حَرَجٌ ۗ وَمَنْ يُطِعِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ يُدْخِلْهُ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۖ وَمَنْ يَتَوَلَّ يُعَذِّبْهُ عَذَابًا أَلِيمًا
Ko si ese fun afoju, ko si ese fun aro, ko si si ese fun alaisan (ti won ko ba lo soju ogun). Enikeni ti o ba tele ti Allahu ati Ojise Re, (Allahu) yoo mu un wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Enikeni ti o ba si gbunri, O maa je e ni iya eleta-elero

Choose other languages: