Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Fath Ayahs #20 Translated in Yoruba

قُلْ لِلْمُخَلَّفِينَ مِنَ الْأَعْرَابِ سَتُدْعَوْنَ إِلَىٰ قَوْمٍ أُولِي بَأْسٍ شَدِيدٍ تُقَاتِلُونَهُمْ أَوْ يُسْلِمُونَ ۖ فَإِنْ تُطِيعُوا يُؤْتِكُمُ اللَّهُ أَجْرًا حَسَنًا ۖ وَإِنْ تَتَوَلَّوْا كَمَا تَوَلَّيْتُمْ مِنْ قَبْلُ يُعَذِّبْكُمْ عَذَابًا أَلِيمًا
So fun awon olusaseyin fun ogun ninu awon Larubawa oko pe: "Won maa pe yin si awon eniyan kan ti won ni agbara ogun jija. E maa ja won logun tabi ki won juwo juse sile (fun ’Islam). Ti eyin ba tele ase (yii), Allahu yoo fun yin ni esan t’o dara. Ti eyin ba si gbunri pada gege bi e se gbunri siwaju, (Allahu) yo si fi iya eleta-elero je yin
لَيْسَ عَلَى الْأَعْمَىٰ حَرَجٌ وَلَا عَلَى الْأَعْرَجِ حَرَجٌ وَلَا عَلَى الْمَرِيضِ حَرَجٌ ۗ وَمَنْ يُطِعِ اللَّهَ وَرَسُولَهُ يُدْخِلْهُ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۖ وَمَنْ يَتَوَلَّ يُعَذِّبْهُ عَذَابًا أَلِيمًا
Ko si ese fun afoju, ko si ese fun aro, ko si si ese fun alaisan (ti won ko ba lo soju ogun). Enikeni ti o ba tele ti Allahu ati Ojise Re, (Allahu) yoo mu un wo inu awon Ogba Idera, eyi ti awon odo n san ni isale re. Enikeni ti o ba si gbunri, O maa je e ni iya eleta-elero
لَقَدْ رَضِيَ اللَّهُ عَنِ الْمُؤْمِنِينَ إِذْ يُبَايِعُونَكَ تَحْتَ الشَّجَرَةِ فَعَلِمَ مَا فِي قُلُوبِهِمْ فَأَنْزَلَ السَّكِينَةَ عَلَيْهِمْ وَأَثَابَهُمْ فَتْحًا قَرِيبًا
Dajudaju Allahu ti yonu si awon onigbagbo ododo nigba ti won n sadehun fun o labe igi (pe awon ko nii fese fee loju ogun). Nitori naa, (Allahu) mo ohun ti o wa ninu okan won. O si so ifokanbale kale fun won. O si san won ni esan isegun t’o sunmo
وَمَغَانِمَ كَثِيرَةً يَأْخُذُونَهَا ۗ وَكَانَ اللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا
ati awon oro ogun opolopo ti won yoo ri ko. Allahu n je Alagbara, Ologbon
وَعَدَكُمُ اللَّهُ مَغَانِمَ كَثِيرَةً تَأْخُذُونَهَا فَعَجَّلَ لَكُمْ هَٰذِهِ وَكَفَّ أَيْدِيَ النَّاسِ عَنْكُمْ وَلِتَكُونَ آيَةً لِلْمُؤْمِنِينَ وَيَهْدِيَكُمْ صِرَاطًا مُسْتَقِيمًا
Ati pe Allahu sadehun awon oro ogun opolopo ti eyin yoo ri ko fun yin. O si tete mu eyi wa fun yin. O tun ko awon eniyan lowo ro fun yin nitori ki o le je ami kan fun awon onigbagbo ododo ati nitori ki O le fi ese yin rinle soju ona taara (’Islam)

Choose other languages: