Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #264 Translated in Yoruba

وَإِذْ قَالَ إِبْرَاهِيمُ رَبِّ أَرِنِي كَيْفَ تُحْيِي الْمَوْتَىٰ ۖ قَالَ أَوَلَمْ تُؤْمِنْ ۖ قَالَ بَلَىٰ وَلَٰكِنْ لِيَطْمَئِنَّ قَلْبِي ۖ قَالَ فَخُذْ أَرْبَعَةً مِنَ الطَّيْرِ فَصُرْهُنَّ إِلَيْكَ ثُمَّ اجْعَلْ عَلَىٰ كُلِّ جَبَلٍ مِنْهُنَّ جُزْءًا ثُمَّ ادْعُهُنَّ يَأْتِينَكَ سَعْيًا ۚ وَاعْلَمْ أَنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
Nigba ti (Anabi) ’Ibrohim so pe: "Oluwa mi, fi han mi bi Iwo yo se so awon oku di alaaye." (Allahu) so pe: “Se iwo ko gbagbo ni?” O so pe: “Rara, sugbon ki okan mi le bale ni”. (Allahu) so pe: "Mu merin ninu awon eye, ki o so won mole si odo re (ki o pa won, ki o si gun won papo mora won). Leyin naa, fi ipin ninu won sori apata kookan. Leyin naa, pe won. Won maa sare wa ba o. Ki o si mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon
مَثَلُ الَّذِينَ يُنْفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ كَمَثَلِ حَبَّةٍ أَنْبَتَتْ سَبْعَ سَنَابِلَ فِي كُلِّ سُنْبُلَةٍ مِائَةُ حَبَّةٍ ۗ وَاللَّهُ يُضَاعِفُ لِمَنْ يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ
Apejuwe awon t’o n na owo won fun esin Allahu da bi apejuwe koro eso kan ti o hu siri meje jade, ti ogorun-un koro si wa lara siri kookan. Allahu yo se adipele fun eni ti O ba fe. Allahu ni Olugbaaye, Onimo
الَّذِينَ يُنْفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ثُمَّ لَا يُتْبِعُونَ مَا أَنْفَقُوا مَنًّا وَلَا أَذًى ۙ لَهُمْ أَجْرُهُمْ عِنْدَ رَبِّهِمْ وَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Awon t’o n na owo won fun esin Allahu, ti won ko si fi iregun ati ipalara tele ohun ti won na, esan won n be fun won lodo Oluwa won. Iberu ko nii si fun won. Won ko si nii banuje
قَوْلٌ مَعْرُوفٌ وَمَغْفِرَةٌ خَيْرٌ مِنْ صَدَقَةٍ يَتْبَعُهَا أَذًى ۗ وَاللَّهُ غَنِيٌّ حَلِيمٌ
Oro rere ati aforijin loore julo si saraa ti ipalara tele. Allahu si ni Oloro, Alafarada
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُبْطِلُوا صَدَقَاتِكُمْ بِالْمَنِّ وَالْأَذَىٰ كَالَّذِي يُنْفِقُ مَالَهُ رِئَاءَ النَّاسِ وَلَا يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۖ فَمَثَلُهُ كَمَثَلِ صَفْوَانٍ عَلَيْهِ تُرَابٌ فَأَصَابَهُ وَابِلٌ فَتَرَكَهُ صَلْدًا ۖ لَا يَقْدِرُونَ عَلَىٰ شَيْءٍ مِمَّا كَسَبُوا ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْكَافِرِينَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se fi iregun ati ipalara ba awon saraa yin je, bi eni ti n na owo re pelu sekarimi, ko si gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Apejuwe re da bi apejuwe apata kan ti erupe n be lori re. Ojo nla ro si i, o si ko erupe kuro lori re patapata. Won ko ni agbara lori kini kan ninu ohun ti won se nise. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo

Choose other languages: