Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #266 Translated in Yoruba

الَّذِينَ يُنْفِقُونَ أَمْوَالَهُمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ثُمَّ لَا يُتْبِعُونَ مَا أَنْفَقُوا مَنًّا وَلَا أَذًى ۙ لَهُمْ أَجْرُهُمْ عِنْدَ رَبِّهِمْ وَلَا خَوْفٌ عَلَيْهِمْ وَلَا هُمْ يَحْزَنُونَ
Awon t’o n na owo won fun esin Allahu, ti won ko si fi iregun ati ipalara tele ohun ti won na, esan won n be fun won lodo Oluwa won. Iberu ko nii si fun won. Won ko si nii banuje
قَوْلٌ مَعْرُوفٌ وَمَغْفِرَةٌ خَيْرٌ مِنْ صَدَقَةٍ يَتْبَعُهَا أَذًى ۗ وَاللَّهُ غَنِيٌّ حَلِيمٌ
Oro rere ati aforijin loore julo si saraa ti ipalara tele. Allahu si ni Oloro, Alafarada
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تُبْطِلُوا صَدَقَاتِكُمْ بِالْمَنِّ وَالْأَذَىٰ كَالَّذِي يُنْفِقُ مَالَهُ رِئَاءَ النَّاسِ وَلَا يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۖ فَمَثَلُهُ كَمَثَلِ صَفْوَانٍ عَلَيْهِ تُرَابٌ فَأَصَابَهُ وَابِلٌ فَتَرَكَهُ صَلْدًا ۖ لَا يَقْدِرُونَ عَلَىٰ شَيْءٍ مِمَّا كَسَبُوا ۗ وَاللَّهُ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الْكَافِرِينَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se fi iregun ati ipalara ba awon saraa yin je, bi eni ti n na owo re pelu sekarimi, ko si gbagbo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Apejuwe re da bi apejuwe apata kan ti erupe n be lori re. Ojo nla ro si i, o si ko erupe kuro lori re patapata. Won ko ni agbara lori kini kan ninu ohun ti won se nise. Allahu ko nii fi ona mo ijo alaigbagbo
وَمَثَلُ الَّذِينَ يُنْفِقُونَ أَمْوَالَهُمُ ابْتِغَاءَ مَرْضَاتِ اللَّهِ وَتَثْبِيتًا مِنْ أَنْفُسِهِمْ كَمَثَلِ جَنَّةٍ بِرَبْوَةٍ أَصَابَهَا وَابِلٌ فَآتَتْ أُكُلَهَا ضِعْفَيْنِ فَإِنْ لَمْ يُصِبْهَا وَابِلٌ فَطَلٌّ ۗ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
Apejuwe awon t’o n na owo won lati wa iyonu Allahu ati (nitori) ifeserinle ninu emi won, o da bi apejuwe ogba oko t’o wa lori ile giga kan, ti ojo nla ro si, ti awon eso re si yo jade ni ilopo meji. Ti ojo nla ko ba si ro si i, iri n se si i. Allahu si ni Oluriran nipa ohun ti e n se
أَيَوَدُّ أَحَدُكُمْ أَنْ تَكُونَ لَهُ جَنَّةٌ مِنْ نَخِيلٍ وَأَعْنَابٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ لَهُ فِيهَا مِنْ كُلِّ الثَّمَرَاتِ وَأَصَابَهُ الْكِبَرُ وَلَهُ ذُرِّيَّةٌ ضُعَفَاءُ فَأَصَابَهَا إِعْصَارٌ فِيهِ نَارٌ فَاحْتَرَقَتْ ۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ لَعَلَّكُمْ تَتَفَكَّرُونَ
Nje eni kan ninu yin nifee si ki oun ni ogba oko dabinu ati ajara, ti awon odo n san ni abe re, ti orisirisi eso tun wa fun un ninu re, ki ogbo de ba a, o si ni awon omo weere ti ko lagbara (ise oko sise), ki ategun lile ti ina n be ninu re kolu oko naa, ki o si jona? Bayen ni Allahu se n s’alaye awon ayah naa fun yin nitori ki e le ronu jinle

Choose other languages: