Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #205 Translated in Yoruba

وَمِنْهُمْ مَنْ يَقُولُ رَبَّنَا آتِنَا فِي الدُّنْيَا حَسَنَةً وَفِي الْآخِرَةِ حَسَنَةً وَقِنَا عَذَابَ النَّارِ
O si n be ninu won, eni t’o n so pe: "Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye ati oore ni orun, ki O si so wa nibi iya Ina
أُولَٰئِكَ لَهُمْ نَصِيبٌ مِمَّا كَسَبُوا ۚ وَاللَّهُ سَرِيعُ الْحِسَابِ
Awon wonyen, tiwon ni ipin oore nipa ohun ti won se nise. Allahu si ni Oluyara nibi isiro-ise
وَاذْكُرُوا اللَّهَ فِي أَيَّامٍ مَعْدُودَاتٍ ۚ فَمَنْ تَعَجَّلَ فِي يَوْمَيْنِ فَلَا إِثْمَ عَلَيْهِ وَمَنْ تَأَخَّرَ فَلَا إِثْمَ عَلَيْهِ ۚ لِمَنِ اتَّقَىٰ ۗ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّكُمْ إِلَيْهِ تُحْشَرُونَ
E seranti Allahu laaarin awon ojo t’o ni onka. Nitori naa, eni ti o ba kanju (se e) fun ojo meji, ko si ese fun un. Eni ti o ba keyin (ti o duro di ojo keta), ko si ese fun un fun eni ti o ba sora (fun iwa ese). E beru Allahu. Ki e si mo pe dajudaju won yoo ko yin jo si odo Re
وَمِنَ النَّاسِ مَنْ يُعْجِبُكَ قَوْلُهُ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا وَيُشْهِدُ اللَّهَ عَلَىٰ مَا فِي قَلْبِهِ وَهُوَ أَلَدُّ الْخِصَامِ
O n be ninu awon eniyan, eni ti oro (enu) re yo maa se o ni kayefi ninu isemi aye yii, ti yo si maa fi Allahu jerii si ohun ti n be ninu okan re (pe ko si ija), onija t’o le julo si ni
وَإِذَا تَوَلَّىٰ سَعَىٰ فِي الْأَرْضِ لِيُفْسِدَ فِيهَا وَيُهْلِكَ الْحَرْثَ وَالنَّسْلَ ۗ وَاللَّهُ لَا يُحِبُّ الْفَسَادَ
Nigba ti o ba si yise pada, o maa sise kiri lori ile nitori ki o le sebaje sori ile, ki o si le pa nnkan oko ati eran-osin run. Allahu ko si feran ibaje

Choose other languages: