Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #142 Translated in Yoruba

صِبْغَةَ اللَّهِ ۖ وَمَنْ أَحْسَنُ مِنَ اللَّهِ صِبْغَةً ۖ وَنَحْنُ لَهُ عَابِدُونَ
(E duro ti) aro Allahu. Ta si l’o dara ju Allahu lo ni aro! Awa si ni olujosin fun Un
قُلْ أَتُحَاجُّونَنَا فِي اللَّهِ وَهُوَ رَبُّنَا وَرَبُّكُمْ وَلَنَا أَعْمَالُنَا وَلَكُمْ أَعْمَالُكُمْ وَنَحْنُ لَهُ مُخْلِصُونَ
So pe: “Se eyin yo ja wa niyan nipa Allahu ni?” Oun si ni Oluwa wa ati Oluwa yin. Tiwa ni awon ise wa. Tiyin si ni awon ise yin. Awa (musulumi) si ni olusafomo-esin fun Un
أَمْ تَقُولُونَ إِنَّ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَالْأَسْبَاطَ كَانُوا هُودًا أَوْ نَصَارَىٰ ۗ قُلْ أَأَنْتُمْ أَعْلَمُ أَمِ اللَّهُ ۗ وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنْ كَتَمَ شَهَادَةً عِنْدَهُ مِنَ اللَّهِ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ
Tabi e n wi pe: “Dajudaju (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub ati awon aromodomo Ya‘ƙub, won je yehudi tabi nasara.” So pe: “Se eyin l’e nimo julo (nipa won ni) tabi Allahu?” Ta l’o sabosi ju eni t’o daso bo eri odo re (ti o sokale) lati odo Allahu? Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise
تِلْكَ أُمَّةٌ قَدْ خَلَتْ ۖ لَهَا مَا كَسَبَتْ وَلَكُمْ مَا كَسَبْتُمْ ۖ وَلَا تُسْأَلُونَ عَمَّا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Ijo kan niyen ti o ti lo. Tiwon ni ohun ti won se nise. Tiyin ni ohun ti e se nise. Won ko si nii bi yin leere nipa ohun ti won n se nise
سَيَقُولُ السُّفَهَاءُ مِنَ النَّاسِ مَا وَلَّاهُمْ عَنْ قِبْلَتِهِمُ الَّتِي كَانُوا عَلَيْهَا ۚ قُلْ لِلَّهِ الْمَشْرِقُ وَالْمَغْرِبُ ۚ يَهْدِي مَنْ يَشَاءُ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ
Awon omugo ninu awon eniyan maa wi pe: “Ki ni o mu won yi kuro nibi Ƙiblah won ti won ti wa tele?” So pe: “Ti Allahu ni ibuyo oorun ati ibuwo oorun. O si n to eni ti O ba fe si ona taara (’Islam).”

Choose other languages: