Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #144 Translated in Yoruba

أَمْ تَقُولُونَ إِنَّ إِبْرَاهِيمَ وَإِسْمَاعِيلَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ وَالْأَسْبَاطَ كَانُوا هُودًا أَوْ نَصَارَىٰ ۗ قُلْ أَأَنْتُمْ أَعْلَمُ أَمِ اللَّهُ ۗ وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنْ كَتَمَ شَهَادَةً عِنْدَهُ مِنَ اللَّهِ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا تَعْمَلُونَ
Tabi e n wi pe: “Dajudaju (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ismo‘il, ’Ishaƙ, Ya‘ƙub ati awon aromodomo Ya‘ƙub, won je yehudi tabi nasara.” So pe: “Se eyin l’e nimo julo (nipa won ni) tabi Allahu?” Ta l’o sabosi ju eni t’o daso bo eri odo re (ti o sokale) lati odo Allahu? Allahu ko si nii gbagbe ohun ti e n se nise
تِلْكَ أُمَّةٌ قَدْ خَلَتْ ۖ لَهَا مَا كَسَبَتْ وَلَكُمْ مَا كَسَبْتُمْ ۖ وَلَا تُسْأَلُونَ عَمَّا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Ijo kan niyen ti o ti lo. Tiwon ni ohun ti won se nise. Tiyin ni ohun ti e se nise. Won ko si nii bi yin leere nipa ohun ti won n se nise
سَيَقُولُ السُّفَهَاءُ مِنَ النَّاسِ مَا وَلَّاهُمْ عَنْ قِبْلَتِهِمُ الَّتِي كَانُوا عَلَيْهَا ۚ قُلْ لِلَّهِ الْمَشْرِقُ وَالْمَغْرِبُ ۚ يَهْدِي مَنْ يَشَاءُ إِلَىٰ صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ
Awon omugo ninu awon eniyan maa wi pe: “Ki ni o mu won yi kuro nibi Ƙiblah won ti won ti wa tele?” So pe: “Ti Allahu ni ibuyo oorun ati ibuwo oorun. O si n to eni ti O ba fe si ona taara (’Islam).”
وَكَذَٰلِكَ جَعَلْنَاكُمْ أُمَّةً وَسَطًا لِتَكُونُوا شُهَدَاءَ عَلَى النَّاسِ وَيَكُونَ الرَّسُولُ عَلَيْكُمْ شَهِيدًا ۗ وَمَا جَعَلْنَا الْقِبْلَةَ الَّتِي كُنْتَ عَلَيْهَا إِلَّا لِنَعْلَمَ مَنْ يَتَّبِعُ الرَّسُولَ مِمَّنْ يَنْقَلِبُ عَلَىٰ عَقِبَيْهِ ۚ وَإِنْ كَانَتْ لَكَبِيرَةً إِلَّا عَلَى الَّذِينَ هَدَى اللَّهُ ۗ وَمَا كَانَ اللَّهُ لِيُضِيعَ إِيمَانَكُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ بِالنَّاسِ لَرَءُوفٌ رَحِيمٌ
Bayen ni A ti se yin ni esa ijo t’o loore julo, nitori ki e le je elerii fun awon eniyan, ati nitori ki Ojise naa le je elerii fun yin. A ko si se Ƙiblah ti o wa lori re tele ni ibukoju-kirun bi ko se pe nitori ki A le se afihan eni ti o maa tele Ojise yato si eni ti o maa yise pada. Dajudaju o lagbara ayafi fun awon ti Allahu to sona. Allahu ko si nii fi igbagbo yin rare. Dajudaju Allahu ni Alaaanu, Onikee fun awon eniyan
قَدْ نَرَىٰ تَقَلُّبَ وَجْهِكَ فِي السَّمَاءِ ۖ فَلَنُوَلِّيَنَّكَ قِبْلَةً تَرْضَاهَا ۚ فَوَلِّ وَجْهَكَ شَطْرَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ ۚ وَحَيْثُ مَا كُنْتُمْ فَوَلُّوا وُجُوهَكُمْ شَطْرَهُ ۗ وَإِنَّ الَّذِينَ أُوتُوا الْكِتَابَ لَيَعْلَمُونَ أَنَّهُ الْحَقُّ مِنْ رَبِّهِمْ ۗ وَمَا اللَّهُ بِغَافِلٍ عَمَّا يَعْمَلُونَ
A kuku ri yiyi ti o n yi oju re si sanmo. Nitori naa, A o doju re ko Ƙiblah kan ti o yonu si; nitori naa, koju re si agbegbe Mosalasi Haram (ni Mokkah). Ibikibi ti e ba tun wa, e koju yin si agbegbe re. Dajudaju awon ti A fun ni Tira kuku mo pe dajudaju ododo ni (ase Ƙiblah) lati odo Oluwa won. Allahu ko si nii gbagbe ohun ti won n se nise

Choose other languages: