Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #117 Translated in Yoruba

وَقَالَتِ الْيَهُودُ لَيْسَتِ النَّصَارَىٰ عَلَىٰ شَيْءٍ وَقَالَتِ النَّصَارَىٰ لَيْسَتِ الْيَهُودُ عَلَىٰ شَيْءٍ وَهُمْ يَتْلُونَ الْكِتَابَ ۗ كَذَٰلِكَ قَالَ الَّذِينَ لَا يَعْلَمُونَ مِثْلَ قَوْلِهِمْ ۚ فَاللَّهُ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ يَوْمَ الْقِيَامَةِ فِيمَا كَانُوا فِيهِ يَخْتَلِفُونَ
Awon yehudi wi pe: “Awon nasara ko ri nnkan kan se (ninu esin).” Awon nasara naa wi pe: “Awon yehudi ko ri nnkan kan se (ninu esin.)” Won si n ke Tira! Bayen ni awon ti ko nimo se so iru oro won (yii). Nitori naa, Allahu a dajo laaarin won ni Ojo Ajinde nipa ohun ti won n yapa enu si
وَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنْ مَنَعَ مَسَاجِدَ اللَّهِ أَنْ يُذْكَرَ فِيهَا اسْمُهُ وَسَعَىٰ فِي خَرَابِهَا ۚ أُولَٰئِكَ مَا كَانَ لَهُمْ أَنْ يَدْخُلُوهَا إِلَّا خَائِفِينَ ۚ لَهُمْ فِي الدُّنْيَا خِزْيٌ وَلَهُمْ فِي الْآخِرَةِ عَذَابٌ عَظِيمٌ
Ati pe ta l’o sabosi ju eni ti o se awon mosalasi Allahu ni eewo lati seranti oruko Allahu ninu re, ti o tun sise lori iparun awon mosalasi naa? Awon wonyen, ko letoo fun won lati wo inu re ayafi pelu iberu. Abuku n be fun won n’ile aye. Ni orun, iya nla si n be fun won
وَلِلَّهِ الْمَشْرِقُ وَالْمَغْرِبُ ۚ فَأَيْنَمَا تُوَلُّوا فَثَمَّ وَجْهُ اللَّهِ ۚ إِنَّ اللَّهَ وَاسِعٌ عَلِيمٌ
Ti Allahu ni ibuyo oorun ati ibuwo oorun. Nitori naa, ibikibi ti e ba doju ko ibe yen naa ni ƙiblah Allahu. Dajudaju Allahu ni Olugbaaye, Onimo
وَقَالُوا اتَّخَذَ اللَّهُ وَلَدًا ۗ سُبْحَانَهُ ۖ بَلْ لَهُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ كُلٌّ لَهُ قَانِتُونَ
Won wi pe: “Allahu so eni kan di omo.” Mimo ni fun Un! Oro ko ri bee, (amo) tiRe ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ile. Eni kookan si ni olutele-ase Re
بَدِيعُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ وَإِذَا قَضَىٰ أَمْرًا فَإِنَّمَا يَقُولُ لَهُ كُنْ فَيَكُونُ
Olupileda awon sanmo ati ile ni (Allahu). Nigba ti O ba si pebubu kini kan, O kan maa so fun un pe: “Je bee.” O si maa je bee

Choose other languages: