Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #108 Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَقُولُوا رَاعِنَا وَقُولُوا انْظُرْنَا وَاسْمَعُوا ۗ وَلِلْكَافِرِينَ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma so pe “ro‘ina”. (Amo) e so pe “unthurna” , ki e si maa teti gbo (oro esin). Iya eleta-elero si wa fun awon alaigbagbo
مَا يَوَدُّ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ وَلَا الْمُشْرِكِينَ أَنْ يُنَزَّلَ عَلَيْكُمْ مِنْ خَيْرٍ مِنْ رَبِّكُمْ ۗ وَاللَّهُ يَخْتَصُّ بِرَحْمَتِهِ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ ذُو الْفَضْلِ الْعَظِيمِ
Awon t’o sai gbagbo ninu awon ti A fun ni Tira ati awon osebo ko fe ki won so oore kan kan kale fun yin lati odo Oluwa yin. Allahu si n fi ike Re sa eni ti O ba fe lesa. Allahu si ni Oloore nla
مَا نَنْسَخْ مِنْ آيَةٍ أَوْ نُنْسِهَا نَأْتِ بِخَيْرٍ مِنْهَا أَوْ مِثْلِهَا ۗ أَلَمْ تَعْلَمْ أَنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
A o nii fi ayah kan pa ayah kan re tabi ki A fi sile (bee ni ohun kike nikan), A maa mu eyi t’o dara ju u lo tabi iru re wa. Se iwo ko mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan
أَلَمْ تَعْلَمْ أَنَّ اللَّهَ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَمَا لَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Se iwo ko mo pe dajudaju ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile? Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu
أَمْ تُرِيدُونَ أَنْ تَسْأَلُوا رَسُولَكُمْ كَمَا سُئِلَ مُوسَىٰ مِنْ قَبْلُ ۗ وَمَنْ يَتَبَدَّلِ الْكُفْرَ بِالْإِيمَانِ فَقَدْ ضَلَّ سَوَاءَ السَّبِيلِ
Tabi e fe maa beere (orokoro) lowo Ojise yin ni gege bi won se beere (orokoro) lowo (Anabi) Musa siwaju? Enikeni ti o ba fi aigbagbo ropo igbagbo, dajudaju o ti sina (kuro) l’oju ona taara

Choose other languages: