Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #110 Translated in Yoruba

مَا نَنْسَخْ مِنْ آيَةٍ أَوْ نُنْسِهَا نَأْتِ بِخَيْرٍ مِنْهَا أَوْ مِثْلِهَا ۗ أَلَمْ تَعْلَمْ أَنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
A o nii fi ayah kan pa ayah kan re tabi ki A fi sile (bee ni ohun kike nikan), A maa mu eyi t’o dara ju u lo tabi iru re wa. Se iwo ko mo pe dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan
أَلَمْ تَعْلَمْ أَنَّ اللَّهَ لَهُ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۗ وَمَا لَكُمْ مِنْ دُونِ اللَّهِ مِنْ وَلِيٍّ وَلَا نَصِيرٍ
Se iwo ko mo pe dajudaju ti Allahu ni ijoba awon sanmo ati ile? Ko si si alaabo ati alaranse kan fun yin leyin Allahu
أَمْ تُرِيدُونَ أَنْ تَسْأَلُوا رَسُولَكُمْ كَمَا سُئِلَ مُوسَىٰ مِنْ قَبْلُ ۗ وَمَنْ يَتَبَدَّلِ الْكُفْرَ بِالْإِيمَانِ فَقَدْ ضَلَّ سَوَاءَ السَّبِيلِ
Tabi e fe maa beere (orokoro) lowo Ojise yin ni gege bi won se beere (orokoro) lowo (Anabi) Musa siwaju? Enikeni ti o ba fi aigbagbo ropo igbagbo, dajudaju o ti sina (kuro) l’oju ona taara
وَدَّ كَثِيرٌ مِنْ أَهْلِ الْكِتَابِ لَوْ يَرُدُّونَكُمْ مِنْ بَعْدِ إِيمَانِكُمْ كُفَّارًا حَسَدًا مِنْ عِنْدِ أَنْفُسِهِمْ مِنْ بَعْدِ مَا تَبَيَّنَ لَهُمُ الْحَقُّ ۖ فَاعْفُوا وَاصْفَحُوا حَتَّىٰ يَأْتِيَ اللَّهُ بِأَمْرِهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Opolopo ninu awon ti A fun ni Tira n fe lati da yin pada sipo keferi leyin ti e ti ni igbagbo ododo, ni ti keeta lati inu emi won, (ati) leyin ti ododo (’Islam) ti foju han si won. Nitori naa, e forijin won, ki e samoju kuro fun won (nipa inira ti won n fi kan yin) titi Allahu yo fi mu ase Re wa (lati ja won logun). Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan
وَأَقِيمُوا الصَّلَاةَ وَآتُوا الزَّكَاةَ ۚ وَمَا تُقَدِّمُوا لِأَنْفُسِكُمْ مِنْ خَيْرٍ تَجِدُوهُ عِنْدَ اللَّهِ ۗ إِنَّ اللَّهَ بِمَا تَعْمَلُونَ بَصِيرٌ
E kirun, e yo Zakah; ohunkohun ti e ba si ti siwaju fun emi ara yin ni rere, e maa ba a lodo Allahu. Dajudaju Allahu ni Oluriran nipa ohun ti e n se nise

Choose other languages: