Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #174 Translated in Yoruba

وَالَّذِينَ يُمَسِّكُونَ بِالْكِتَابِ وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ إِنَّا لَا نُضِيعُ أَجْرَ الْمُصْلِحِينَ
Awon t’o n mu Tira lo daradara, ti won n kirun, dajudaju Awa ko nii fi esan awon t’o n se atunse (ise won) rare
وَإِذْ نَتَقْنَا الْجَبَلَ فَوْقَهُمْ كَأَنَّهُ ظُلَّةٌ وَظَنُّوا أَنَّهُ وَاقِعٌ بِهِمْ خُذُوا مَا آتَيْنَاكُمْ بِقُوَّةٍ وَاذْكُرُوا مَا فِيهِ لَعَلَّكُمْ تَتَّقُونَ
(Ranti) nigba ti A gbe apata ga soke ori won, o si da bi iboji. Won si lero pe o maa wo lu awon mole, (A si so fun won pe): “E gba ohun ti A fun yin mu daadaa, ki e si maa ranti ohun t’o n be ninu re, nitori ki e le beru (Allahu).”
وَإِذْ أَخَذَ رَبُّكَ مِنْ بَنِي آدَمَ مِنْ ظُهُورِهِمْ ذُرِّيَّتَهُمْ وَأَشْهَدَهُمْ عَلَىٰ أَنْفُسِهِمْ أَلَسْتُ بِرَبِّكُمْ ۖ قَالُوا بَلَىٰ ۛ شَهِدْنَا ۛ أَنْ تَقُولُوا يَوْمَ الْقِيَامَةِ إِنَّا كُنَّا عَنْ هَٰذَا غَافِلِينَ
(Ranti) nigba ti Oluwa re gba adehun lowo awon omo Adam, O fa aromodomo won jade lati (ibadi ni) eyin (baba nla) won, O si fi won se elerii lori ara won pe: “Se Emi ko ni Oluwa yin ni?” Won so pe: “Rara – (Iwo ni Oluwa wa) - a jerii si i.” Nitori ki e ma baa so ni Ojo Ajinde pe: "Dajudaju awa je alaimo nipa eyi
أَوْ تَقُولُوا إِنَّمَا أَشْرَكَ آبَاؤُنَا مِنْ قَبْلُ وَكُنَّا ذُرِّيَّةً مِنْ بَعْدِهِمْ ۖ أَفَتُهْلِكُنَا بِمَا فَعَلَ الْمُبْطِلُونَ
Tabi ki e ma baa wi pe: “Awon baba wa lo kuku ba Allahu wa akegbe siwaju (wa), awa si je aromodomo leyin won (ni a fi wo won kose pelu aimokan). Se Iwo yoo pa wa run nitori ohun ti awon t’o n tele iro se ni?”
وَكَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ وَلَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Bayen ni A se n salaye awon ayah Wa, nitori ki won le seri pada (sibi ododo)

Choose other languages: