Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #177 Translated in Yoruba

أَوْ تَقُولُوا إِنَّمَا أَشْرَكَ آبَاؤُنَا مِنْ قَبْلُ وَكُنَّا ذُرِّيَّةً مِنْ بَعْدِهِمْ ۖ أَفَتُهْلِكُنَا بِمَا فَعَلَ الْمُبْطِلُونَ
Tabi ki e ma baa wi pe: “Awon baba wa lo kuku ba Allahu wa akegbe siwaju (wa), awa si je aromodomo leyin won (ni a fi wo won kose pelu aimokan). Se Iwo yoo pa wa run nitori ohun ti awon t’o n tele iro se ni?”
وَكَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ وَلَعَلَّهُمْ يَرْجِعُونَ
Bayen ni A se n salaye awon ayah Wa, nitori ki won le seri pada (sibi ododo)
وَاتْلُ عَلَيْهِمْ نَبَأَ الَّذِي آتَيْنَاهُ آيَاتِنَا فَانْسَلَخَ مِنْهَا فَأَتْبَعَهُ الشَّيْطَانُ فَكَانَ مِنَ الْغَاوِينَ
Ka iroyin eni ti A fun ni awon ayah Wa fun won, ti o yora re sile nibi awon ayah naa. Nitori naa, Esu tele e leyin. O si wa ninu awon olusina
وَلَوْ شِئْنَا لَرَفَعْنَاهُ بِهَا وَلَٰكِنَّهُ أَخْلَدَ إِلَى الْأَرْضِ وَاتَّبَعَ هَوَاهُ ۚ فَمَثَلُهُ كَمَثَلِ الْكَلْبِ إِنْ تَحْمِلْ عَلَيْهِ يَلْهَثْ أَوْ تَتْرُكْهُ يَلْهَثْ ۚ ذَٰلِكَ مَثَلُ الْقَوْمِ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا ۚ فَاقْصُصِ الْقَصَصَ لَعَلَّهُمْ يَتَفَكَّرُونَ
Ati pe ti o ba je pe A ba fe, Awa iba fi (imo nipa awon ayah Wa) sagbega fun un. Sugbon o waye moya. O si tele ife-inu re. Nitori naa, afiwe re da bi aja. Ti o ba le e siwaju, o maa yo ahon sita. Ti o ba si fi sile, o tun maa yo ahon sita. Iyen ni afiwe ijo t’o pe awon ayah Wa niro. So itan naa fun won nitori ki won le ronu jinle
سَاءَ مَثَلًا الْقَوْمُ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَأَنْفُسَهُمْ كَانُوا يَظْلِمُونَ
Ijo ti o pe awon ayah Wa niro, won buru ni afiwe. Ara won si ni won n sabosi si

Choose other languages: