Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #180 Translated in Yoruba

وَلَوْ شِئْنَا لَرَفَعْنَاهُ بِهَا وَلَٰكِنَّهُ أَخْلَدَ إِلَى الْأَرْضِ وَاتَّبَعَ هَوَاهُ ۚ فَمَثَلُهُ كَمَثَلِ الْكَلْبِ إِنْ تَحْمِلْ عَلَيْهِ يَلْهَثْ أَوْ تَتْرُكْهُ يَلْهَثْ ۚ ذَٰلِكَ مَثَلُ الْقَوْمِ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا ۚ فَاقْصُصِ الْقَصَصَ لَعَلَّهُمْ يَتَفَكَّرُونَ
Ati pe ti o ba je pe A ba fe, Awa iba fi (imo nipa awon ayah Wa) sagbega fun un. Sugbon o waye moya. O si tele ife-inu re. Nitori naa, afiwe re da bi aja. Ti o ba le e siwaju, o maa yo ahon sita. Ti o ba si fi sile, o tun maa yo ahon sita. Iyen ni afiwe ijo t’o pe awon ayah Wa niro. So itan naa fun won nitori ki won le ronu jinle
سَاءَ مَثَلًا الْقَوْمُ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَأَنْفُسَهُمْ كَانُوا يَظْلِمُونَ
Ijo ti o pe awon ayah Wa niro, won buru ni afiwe. Ara won si ni won n sabosi si
مَنْ يَهْدِ اللَّهُ فَهُوَ الْمُهْتَدِي ۖ وَمَنْ يُضْلِلْ فَأُولَٰئِكَ هُمُ الْخَاسِرُونَ
Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), oun ni olumona. Enikeni ti O ba si si lona, awon wonyen, awon ni eni ofo
وَلَقَدْ ذَرَأْنَا لِجَهَنَّمَ كَثِيرًا مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنْسِ ۖ لَهُمْ قُلُوبٌ لَا يَفْقَهُونَ بِهَا وَلَهُمْ أَعْيُنٌ لَا يُبْصِرُونَ بِهَا وَلَهُمْ آذَانٌ لَا يَسْمَعُونَ بِهَا ۚ أُولَٰئِكَ كَالْأَنْعَامِ بَلْ هُمْ أَضَلُّ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الْغَافِلُونَ
Dajudaju A ti da opolopo eniyan ati alujannu fun ina Jahanamo (nitori pe) won ni okan, won ko si fi gbo agboye; won ni oju, won ko si fi riran; won ni eti, won ko si fi gboran. Awon wonyen da bi eran-osin. Won wule sonu julo. Awon wonyen, awon ni afonu-fora
وَلِلَّهِ الْأَسْمَاءُ الْحُسْنَىٰ فَادْعُوهُ بِهَا ۖ وَذَرُوا الَّذِينَ يُلْحِدُونَ فِي أَسْمَائِهِ ۚ سَيُجْزَوْنَ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Ti Allahu ni awon oruko t’o dara julo. Nitori naa, e fi pe E. Ki e si pa awon t’o n ye kuro nibi awon oruko Re ti. A oo san won ni esan ohun ti won n se nise

Choose other languages: