Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #154 Translated in Yoruba

وَلَمَّا رَجَعَ مُوسَىٰ إِلَىٰ قَوْمِهِ غَضْبَانَ أَسِفًا قَالَ بِئْسَمَا خَلَفْتُمُونِي مِنْ بَعْدِي ۖ أَعَجِلْتُمْ أَمْرَ رَبِّكُمْ ۖ وَأَلْقَى الْأَلْوَاحَ وَأَخَذَ بِرَأْسِ أَخِيهِ يَجُرُّهُ إِلَيْهِ ۚ قَالَ ابْنَ أُمَّ إِنَّ الْقَوْمَ اسْتَضْعَفُونِي وَكَادُوا يَقْتُلُونَنِي فَلَا تُشْمِتْ بِيَ الْأَعْدَاءَ وَلَا تَجْعَلْنِي مَعَ الْقَوْمِ الظَّالِمِينَ
Nigba ti (Anabi) Musa si pada si odo ijo re pelu ibinu ati ibanuje, o so pe: “Ohun ti e fi role de mi leyin mi buru. Se e ti kanju pa ase Oluwa yin ti ni?" O si ju awon walaa sile, o gba ori arakunrin re mu, o si n wo o mora. (Harun) so pe: “Omo iya mi o, dajudaju awon eniyan ni won foju tinrin mi, won si fee pa mi. Nitori naa, ma se je ki awon ota yo mi. Ma si se mu mi mo ijo alabosi.”
قَالَ رَبِّ اغْفِرْ لِي وَلِأَخِي وَأَدْخِلْنَا فِي رَحْمَتِكَ ۖ وَأَنْتَ أَرْحَمُ الرَّاحِمِينَ
(Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, forijin emi ati arakunrin mi. Ki O si fi wa sinu ike Re. Iwo si ni Alaaanu-julo ninu awon alaaanu.”
إِنَّ الَّذِينَ اتَّخَذُوا الْعِجْلَ سَيَنَالُهُمْ غَضَبٌ مِنْ رَبِّهِمْ وَذِلَّةٌ فِي الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُفْتَرِينَ
Dajudaju awon t’o so (ere) omo maalu di akunlebo, ibinu lati odo Oluwa won ati iyepere yoo ba won ninu isemi aye yii. Bayen ni A se n san awon aladapa iro ni esan
وَالَّذِينَ عَمِلُوا السَّيِّئَاتِ ثُمَّ تَابُوا مِنْ بَعْدِهَا وَآمَنُوا إِنَّ رَبَّكَ مِنْ بَعْدِهَا لَغَفُورٌ رَحِيمٌ
Awon t’o si se awon ise aburu, leyin naa ti won ronu piwada leyin re, ti won si gbagbo ni ododo, dajudaju leyin eyi Oluwa re ni Alaforijin, Asake-orun
وَلَمَّا سَكَتَ عَنْ مُوسَى الْغَضَبُ أَخَذَ الْأَلْوَاحَ ۖ وَفِي نُسْخَتِهَا هُدًى وَرَحْمَةٌ لِلَّذِينَ هُمْ لِرَبِّهِمْ يَرْهَبُونَ
Nigba ti ibinu (Anabi) Musa si wale, o mu awon walaa naa. Imona ati aanu n be ninu akosile re fun awon t’o n beru Oluwa won

Choose other languages: