Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #58 Translated in Yoruba

وَإِذَا جَاءَكَ الَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِآيَاتِنَا فَقُلْ سَلَامٌ عَلَيْكُمْ ۖ كَتَبَ رَبُّكُمْ عَلَىٰ نَفْسِهِ الرَّحْمَةَ ۖ أَنَّهُ مَنْ عَمِلَ مِنْكُمْ سُوءًا بِجَهَالَةٍ ثُمَّ تَابَ مِنْ بَعْدِهِ وَأَصْلَحَ فَأَنَّهُ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Nigba ti awon t’o gba awon ayah Wa gbo ba wa ba o, so (fun won) pe: "Ki alaafia maa ba yin. Oluwa yin se aanu ni oran-anyan lera Re lori pe, dajudaju enikeni ninu yin ti o ba se ise aburu pelu aimokan, leyin naa, ti o ronu piwada leyin re, ti o si se atunse, dajudaju Oun ni Alaforijin, Asake-orun
وَكَذَٰلِكَ نُفَصِّلُ الْآيَاتِ وَلِتَسْتَبِينَ سَبِيلُ الْمُجْرِمِينَ
Bayen ni A se n salaye awon ayah nitori ki ona awon elese le foju han kedere
قُلْ إِنِّي نُهِيتُ أَنْ أَعْبُدَ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ ۚ قُلْ لَا أَتَّبِعُ أَهْوَاءَكُمْ ۙ قَدْ ضَلَلْتُ إِذًا وَمَا أَنَا مِنَ الْمُهْتَدِينَ
So pe: “Dajudaju Won ko fun mi lati josin fun awon ti e n pe leyin Allahu.” So pe: “Emi ko nii tele ife-inu yin. Bi bee ko nigba naa, mo ti sina (ti mo ba tele ife-inu yin). Emi ko si si ninu awon olumona.”
قُلْ إِنِّي عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِنْ رَبِّي وَكَذَّبْتُمْ بِهِ ۚ مَا عِنْدِي مَا تَسْتَعْجِلُونَ بِهِ ۚ إِنِ الْحُكْمُ إِلَّا لِلَّهِ ۖ يَقُصُّ الْحَقَّ ۖ وَهُوَ خَيْرُ الْفَاصِلِينَ
So pe: “Dajudaju mo wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, eyin si pe e niro. Ko si ohun ti e n wa pelu ikanju ni odo mi. Ko si idajo naa (fun enikeni) ayafi fun Allahu, Eni ti n so (idajo) ododo. O si loore julo ninu awon oludajo.”
قُلْ لَوْ أَنَّ عِنْدِي مَا تَسْتَعْجِلُونَ بِهِ لَقُضِيَ الْأَمْرُ بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ ۗ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِالظَّالِمِينَ
So pe: “Ti o ba je pe dajudaju ohun ti e n wa pelu ikanju n be ni odo mi ni, Won iba ti se idajo oro naa laaarin emi ati eyin. Allahu si nimo julo nipa awon alabosi.”

Choose other languages: