Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #60 Translated in Yoruba

قُلْ إِنِّي نُهِيتُ أَنْ أَعْبُدَ الَّذِينَ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ ۚ قُلْ لَا أَتَّبِعُ أَهْوَاءَكُمْ ۙ قَدْ ضَلَلْتُ إِذًا وَمَا أَنَا مِنَ الْمُهْتَدِينَ
So pe: “Dajudaju Won ko fun mi lati josin fun awon ti e n pe leyin Allahu.” So pe: “Emi ko nii tele ife-inu yin. Bi bee ko nigba naa, mo ti sina (ti mo ba tele ife-inu yin). Emi ko si si ninu awon olumona.”
قُلْ إِنِّي عَلَىٰ بَيِّنَةٍ مِنْ رَبِّي وَكَذَّبْتُمْ بِهِ ۚ مَا عِنْدِي مَا تَسْتَعْجِلُونَ بِهِ ۚ إِنِ الْحُكْمُ إِلَّا لِلَّهِ ۖ يَقُصُّ الْحَقَّ ۖ وَهُوَ خَيْرُ الْفَاصِلِينَ
So pe: “Dajudaju mo wa lori eri t’o yanju lati odo Oluwa mi, eyin si pe e niro. Ko si ohun ti e n wa pelu ikanju ni odo mi. Ko si idajo naa (fun enikeni) ayafi fun Allahu, Eni ti n so (idajo) ododo. O si loore julo ninu awon oludajo.”
قُلْ لَوْ أَنَّ عِنْدِي مَا تَسْتَعْجِلُونَ بِهِ لَقُضِيَ الْأَمْرُ بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ ۗ وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِالظَّالِمِينَ
So pe: “Ti o ba je pe dajudaju ohun ti e n wa pelu ikanju n be ni odo mi ni, Won iba ti se idajo oro naa laaarin emi ati eyin. Allahu si nimo julo nipa awon alabosi.”
وَعِنْدَهُ مَفَاتِحُ الْغَيْبِ لَا يَعْلَمُهَا إِلَّا هُوَ ۚ وَيَعْلَمُ مَا فِي الْبَرِّ وَالْبَحْرِ ۚ وَمَا تَسْقُطُ مِنْ وَرَقَةٍ إِلَّا يَعْلَمُهَا وَلَا حَبَّةٍ فِي ظُلُمَاتِ الْأَرْضِ وَلَا رَطْبٍ وَلَا يَابِسٍ إِلَّا فِي كِتَابٍ مُبِينٍ
Odo Re si ni awon kokoro ikoko wa. Ko si eni t’o nimo re afi Oun. O nimo ohun ti n be ninu ile ati odo. Ewe kan ko si nii ja bo afi ki O nimo re. Ko si si koro eso kan ninu okunkun (inu) ile, ko si ohun tutu tabi gbigbe kan afi ki o wa ninu akosile t’o yanju
وَهُوَ الَّذِي يَتَوَفَّاكُمْ بِاللَّيْلِ وَيَعْلَمُ مَا جَرَحْتُمْ بِالنَّهَارِ ثُمَّ يَبْعَثُكُمْ فِيهِ لِيُقْضَىٰ أَجَلٌ مُسَمًّى ۖ ثُمَّ إِلَيْهِ مَرْجِعُكُمْ ثُمَّ يُنَبِّئُكُمْ بِمَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ
Oun ni Eni t’O n kun yin ni oorun ni ale. O si nimo nipa ohun ti e se nise ni osan. Leyin naa, O n gbe yin dide (fun ije-imu) ni (osan) nitori ki won le pari gbedeke akoko kan. Leyin naa, odo Re ni ibupadasi yin. Leyin naa, O maa fun yin ni iro ohun ti e n se nise

Choose other languages: