Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #30 Translated in Yoruba

وَهُمْ يَنْهَوْنَ عَنْهُ وَيَنْأَوْنَ عَنْهُ ۖ وَإِنْ يُهْلِكُونَ إِلَّا أَنْفُسَهُمْ وَمَا يَشْعُرُونَ
Awon ni won n ko (fun awon eniyan lati tele Anabi s.a.w.), awon naa si n takete si i. Won ko si ko iparun ba enikeni bi ko se emi ara won; won ko si fura
وَلَوْ تَرَىٰ إِذْ وُقِفُوا عَلَى النَّارِ فَقَالُوا يَا لَيْتَنَا نُرَدُّ وَلَا نُكَذِّبَ بِآيَاتِ رَبِّنَا وَنَكُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ
Ti o ba je pe o ri (won ni) nigba ti A ba da won duro sibi Ina, won si maa wi pe: “Yee! Ki won si da wa pada (sile aye), awa ko si nii pe awon ayah Oluwa wa niro (mo), a si maa wa ninu awon onigbagbo ododo.”
بَلْ بَدَا لَهُمْ مَا كَانُوا يُخْفُونَ مِنْ قَبْلُ ۖ وَلَوْ رُدُّوا لَعَادُوا لِمَا نُهُوا عَنْهُ وَإِنَّهُمْ لَكَاذِبُونَ
Ko ri bee, ohun ti won n fi pamo siwaju ti han si won ni. Ti o ba je pe A ba da won pada (sile aye), won yoo kuku pada sibi ohun ti A ko fun won. Dajudaju opuro ma ni won
وَقَالُوا إِنْ هِيَ إِلَّا حَيَاتُنَا الدُّنْيَا وَمَا نَحْنُ بِمَبْعُوثِينَ
Won wi pe: "Ki ni (o tun je isemi orun) bi ko se isemi wa nile aye; Won ko si nii gbe wa dide (ni orun)
وَلَوْ تَرَىٰ إِذْ وُقِفُوا عَلَىٰ رَبِّهِمْ ۚ قَالَ أَلَيْسَ هَٰذَا بِالْحَقِّ ۚ قَالُوا بَلَىٰ وَرَبِّنَا ۚ قَالَ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنْتُمْ تَكْفُرُونَ
Ti o ba je pe o ri (won ni) nigba ti won ba da won duro si odo Oluwa won, O si maa so pe: “Se eyi ki i se ododo bi?” Won a si wi pe: “Rara (ododo ni), Oluwa wa.” (Allahu) so pe: “Nitori naa, e to Iya wo nitori pe e maa n sai gbagbo.”

Choose other languages: