Quran Apps in many lanuages:

Surah Yusuf Ayahs #42 Translated in Yoruba

وَاتَّبَعْتُ مِلَّةَ آبَائِي إِبْرَاهِيمَ وَإِسْحَاقَ وَيَعْقُوبَ ۚ مَا كَانَ لَنَا أَنْ نُشْرِكَ بِاللَّهِ مِنْ شَيْءٍ ۚ ذَٰلِكَ مِنْ فَضْلِ اللَّهِ عَلَيْنَا وَعَلَى النَّاسِ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَشْكُرُونَ
Mo si tele esin awon baba mi, (awon Anabi) ’Ibrohim, ’Ishaƙ ati Ya‘ƙub. Ko to si wa pe ki a so nnkan kan di akegbe fun Allahu. Iyen wa ninu oore ajulo Allahu lori awa ati lori awon eniyan, sugbon opolopo awon eniyan ki i dupe (fun Allahu)
يَا صَاحِبَيِ السِّجْنِ أَأَرْبَابٌ مُتَفَرِّقُونَ خَيْرٌ أَمِ اللَّهُ الْوَاحِدُ الْقَهَّارُ
Eyin akegbe mi mejeeji ninu ewon, se awon oluwa otooto l’o loore julo (lati josin fun) tabi Allahu, Okan soso, Olubori
مَا تَعْبُدُونَ مِنْ دُونِهِ إِلَّا أَسْمَاءً سَمَّيْتُمُوهَا أَنْتُمْ وَآبَاؤُكُمْ مَا أَنْزَلَ اللَّهُ بِهَا مِنْ سُلْطَانٍ ۚ إِنِ الْحُكْمُ إِلَّا لِلَّهِ ۚ أَمَرَ أَلَّا تَعْبُدُوا إِلَّا إِيَّاهُ ۚ ذَٰلِكَ الدِّينُ الْقَيِّمُ وَلَٰكِنَّ أَكْثَرَ النَّاسِ لَا يَعْلَمُونَ
Ko si ohun kan ti e n josin fun leyin Re bi ko se awon oruko kan ti e so won - eyin ati awon baba yin - Allahu ko so eri kan kale fun un. Idajo (ta ni ijosin to si) ko si fun eni kan afi Allahu. O si ti pase pe e ma josin fun kini kan afi Oun nikan. Iyen ni esin t’o fese rinle, sugbon opolopo awon eniyan ko mo
يَا صَاحِبَيِ السِّجْنِ أَمَّا أَحَدُكُمَا فَيَسْقِي رَبَّهُ خَمْرًا ۖ وَأَمَّا الْآخَرُ فَيُصْلَبُ فَتَأْكُلُ الطَّيْرُ مِنْ رَأْسِهِ ۚ قُضِيَ الْأَمْرُ الَّذِي فِيهِ تَسْتَفْتِيَانِ
Eyin akegbe mi mejeeji ninu ewon, ni ti eni kan ninu yin, o maa fun oga re ni oti mu. Ni ti eni keji, won yoo kan an mo igi, eye yo si maa je ninu ori re. Won ti pari oro ti eyin mejeeji n se ibeere nipa re
وَقَالَ لِلَّذِي ظَنَّ أَنَّهُ نَاجٍ مِنْهُمَا اذْكُرْنِي عِنْدَ رَبِّكَ فَأَنْسَاهُ الشَّيْطَانُ ذِكْرَ رَبِّهِ فَلَبِثَ فِي السِّجْنِ بِضْعَ سِنِينَ
O si so fun eni ti o ro pe o maa la ninu awon mejeeji pe: “Ranti mi lodo oga re.” Esu si mu (Yusuf) gbagbe iranti Oluwa re (nipa wiwa iranlowo sodo oga re). Nitori naa, o wa ninu ogba ewon fun awon odun die

Choose other languages: