Quran Apps in many lanuages:

Surah Fatir Ayahs #4 Translated in Yoruba

الْحَمْدُ لِلَّهِ فَاطِرِ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ جَاعِلِ الْمَلَائِكَةِ رُسُلًا أُولِي أَجْنِحَةٍ مَثْنَىٰ وَثُلَاثَ وَرُبَاعَ ۚ يَزِيدُ فِي الْخَلْقِ مَا يَشَاءُ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Gbogbo ope n je ti Allahu, Olupileda awon sanmo ati ile, (Eni ti) O se awon molaika alapa meji ati meta ati merin ni Ojise. O n se alekun ohun ti O ba fe lara eda. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori gbogbo nnkan
مَا يَفْتَحِ اللَّهُ لِلنَّاسِ مِنْ رَحْمَةٍ فَلَا مُمْسِكَ لَهَا ۖ وَمَا يُمْسِكْ فَلَا مُرْسِلَ لَهُ مِنْ بَعْدِهِ ۚ وَهُوَ الْعَزِيزُ الْحَكِيمُ
Ohunkohun ti Allahu ba si ona re sile ninu ike fun awon eniyan, ko si eni ti o le da a duro. Ohunkohun ti O ba si mu dani, ko si eni ti o le mu un wa leyin Re. Oun si ni Alagbara, Ologbon
يَا أَيُّهَا النَّاسُ اذْكُرُوا نِعْمَتَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ ۚ هَلْ مِنْ خَالِقٍ غَيْرُ اللَّهِ يَرْزُقُكُمْ مِنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۚ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ فَأَنَّىٰ تُؤْفَكُونَ
Eyin eniyan, e ranti idera Allahu lori yin. Nje eledaa kan yato si Allahu tun wa ti o n pese fun yin lati inu sanmo ati ile? Ko si olohun ti ijosin to si afi Oun. Nitori naa, bawo ni won se n se yin lori kuro nibi ododo
وَإِنْ يُكَذِّبُوكَ فَقَدْ كُذِّبَتْ رُسُلٌ مِنْ قَبْلِكَ ۚ وَإِلَى اللَّهِ تُرْجَعُ الْأُمُورُ
Ti won ba pe o ni opuro, won kuku ti pe awon Ojise kan ni opuro siwaju re. Odo Allahu si ni won maa seri awon oro eda pada si

Choose other languages: